Awọn Fulani yawọ inu oko alukoro ẹgbẹ oṣelu APC ni Kwara, wọn ṣa awọn eeyan yannayanna - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, June 20, 2021

Awọn Fulani yawọ inu oko alukoro ẹgbẹ oṣelu APC ni Kwara, wọn ṣa awọn eeyan yannayanna


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
 
Ọjọ buruku, eṣu gbomimu lọjọ Ẹti, Furaide to kọja yii jẹ niluu Ọffa, nigba ti wọn lawọn afurasi Fulani darandaran kan yawọ inu oko alukoro ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Kwara, Alaaji Tajudeen Fọlaranmi Aro, nibi ti wọn ti ṣe awọn eeyan yannayanna.
 
Nnkan bi aago mẹfa irọlẹ ọjọ naa la gbọ pe awọn afurasi Fulani darandaran naa da maalu wọn wọnu oko Alaaji Tajudeen Aro, to wa lẹyin yunifasiti Ọffa.

A gbọ pe bi wọn ṣe da maalu wọnu oko yii lawọn agbẹ ti wọn n ṣiṣẹ lọwọ nibẹ ti sunmọn wọn lati le wọn pada, ṣugbọn ti wọn sọ pe ṣe lawọn Fulani naa yọ ada ati awọn nnkan ija oloro ọwọ wọn sawọn agbẹ naa.
 
Nibi ti wọn ti n fa ọrọ naa ni wọn lawọn agbẹ yii ti ṣe pupọ awọn maalu naa leṣe pẹlu erongba lati jẹ kawọn Fulani darandaran naa salọ

A gbọ pe ṣe ni iṣẹlẹ ikọlu naa dabi ogun abẹlẹ, nigba ti wọn lawọ Fulani yii ko woju ẹnikẹni, ti wọn si n ṣa awọn eeyan lada bo ṣe wu wọn.
 
Several injured as suspected Fulani herdsmen attack farm belonging to Kwara APC spokesman 
Nigba ti wọn lawọn agbẹ naa ri i pe agbara wọn ko fẹẹ ka awọn Fulani yii mọ, lo mu ki wọn sare ranṣẹ sawọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi to wa lagbegbe naa fun iranwọ, eyi si ni wọn lo ta si wọn leti, to fi di pe wọn ba ẹsẹ wọn sọrọ, kọọ ma ba a tẹ wọn.
 
Ọgbẹni Babawale Afọlabi to jẹ alukoro ileeṣẹ alaabo Sifu Difẹnsi nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe ṣe lawọn sare gbe ọkan lara awọn agbẹ to farapa, Yakub Salasi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn lọ si ọsibitu kan to wa ni Ilemọna fun itọju.
 
Afọlabi sọ pe awọn yooku ti wọn farapa lawọn gbe lọ si ọsibitu Abdulsalam to wa niluu Ọffa, fun itọju to peye.

Oun gan an lo jẹ ka mọ pe pẹlu iranlọwọ awọn Fijilante lawọn fi wọnu igbo naa lati wa awọn Fulani darandara naa kan, ṣugbọn to ni wọn ti salọ.
 
A gbọ pe ọwọ ti tẹ lara awọn maalu ti wọn da wọnu oko naa, to si ni Fulani kan lagbegbe naa, Alaaji Sabo Yaro ti yọju lati ṣe iranlọwọ bi wọn yoo ṣe ri awọn Fulani darandaran naa mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI