Baba Ijẹṣa bu sẹkun ni kọọtu lẹyin ti ile ẹjọ kọ lati gba beeli ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 16, 2021

Baba Ijẹṣa bu sẹkun ni kọọtu lẹyin ti ile ẹjọ kọ lati gba beeli ẹ


Lonii ni gbajugbaja oṣere tiata adẹrinpoṣonu nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, ẹni tawọn ololufẹ rẹ mọ si Baba Ijẹṣa foju ba ile ẹjọ Majisireeti to wa ni Yaba niluu Eko.

Ẹsun to ni i ṣe pẹlu ifipabanilopọ ni wọn fi kan Baba Ijẹṣa ni nnkan bi oṣu meji sẹyin, to si ti wa latimọle latigba naa, eyi to ti da oriṣiriṣi awuyewuye silẹ nigboro.
 
Oṣu kẹrin ọdun yii lọwọ tẹ Baba Ijẹṣa nibi ti wọn ti fẹsun kan an pe o fẹẹ fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla kan laṣepọ, ti wọn si loo ti kọkọ ko ibasun fọmọ yii nigba to wa lọmọ ọdun meje.
 
Ọjọ kẹtadinlogun oṣu to kọja ni ile ẹjọ paṣẹ pe ki wọn gba beeli oṣere tiata yii lati din ero to wa lawọn ọgba ẹwọn ku, ṣugbọn ti ko ri oniduro fun un lastigba naa.

Lonii ni agbẹjọro baba Ijẹṣa, Kayọde Ọlabiran rawọ ẹbẹ si ile ẹjọ lati fun laaye ko lọ sile lati tọju ara rẹ digba ti igbẹjọ mi in yoo waye. O ni ara Baba Ijẹṣa ko ya gidigidi, ati pe aisan ti wa lara ẹ.

Nigba to n sọrọ, Onidajọ P. E. Nwaka sọ pe oun ko laṣẹ lati fun Baba Ijẹṣa ni beeli nitori pe nnkan to kọja agbara oun. Nwaka sọ pe niwọn igba ti ẹjọ naa tun ti wa niwaju ile ẹjọ giga, ile ẹjọ naa lo ni aṣẹ lọwọ.
 
Bakan naa, ọlọpaa to n bojuto ẹjọ naa, Yetunde Cardoso sọ pe ẹjọ naa ti kọja agbara ọlọpaa lo jẹ ki wọn tete gbe e wa siwaju ile ẹjọ.
 
Niwaju ile ẹjọ naa ni Baba Ijẹṣa ti loun o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun pẹlu alaye, ṣugbọn ti wọn sọ pe ko ṣi tọju awọn alaye rẹ digba ti igbẹjọ mi in yoo waye lọjọ kẹtala oṣu keje ọdun.

Bi ile ẹjọ ṣe loun ko le fun Baba Ijẹṣa ni beeli lọkunrin naa kawọ mọri, to si bẹrẹ si i banujẹ wi pe oun yoo tun pada sọgba ẹwọn, ṣugbọn ti ko si nnkan to fẹẹ ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI