Ọrọ buruku toun tẹrin gba a lọrọ Ṣẹgun ti wọn laṣiri rẹ tu lasiko to n ko ibasun fọmọ ọdun mejila labẹ igi Mangọ ṣi n jẹ titi di asiko ta a pari iroyin yii.
Ṣẹgun Oni, ẹni ọdun mọkandinlogoji lọwọ tẹ lasiko to n fipa ko ibasun fọmọ ọdun mejila naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Amina Ajibade.
Agbegbe kan ti wọn pe ni Ijagbe nijọba ibilẹ Oyun, Ilọrin, ipinlẹ Kwara niṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ kẹrinla oṣu yii, ọjọ Mọnde ijẹta la n sọrọ nipa rẹ.
Ọgbẹni Babawale Zaid Afọlabi, to jẹ alukoro ileeṣẹ ẹṣọ-aabo-ara-ẹni-laabo-ilu, ti wọn n pe ni Sifu Difẹnsi to gbe iroyin naa sita sọ pe baba to bi baba ọmọ naa lo ri Ṣẹgun nibi to ti n ko ibasun fun un karakara.
O ni ileeṣẹ awọn ti ẹkun Igbaja ni wọn lọ fi iṣẹlẹ naa to leti, ko to di pe wọn lọọ gbe Ṣẹgun.
A gbọ pe ara ọmọ naa ko ya daadaa, ti wọn si ni ọpọlọ rẹ ko pe, ti ko si le sọrọ daadaa, anfaani naa ni wọn sọ pe Ṣẹgun lo lati lọọ muna labẹ ẹ, ṣugbọn ti aṣiri rẹ tu.
Iwadii tawọn Sifu Difẹnsi naa ṣe lọsibitu fidi rẹ mulẹ pe wọn ṣẹṣẹ ko ibasun fun un tan ni, ati pe apa loriṣiriṣi bii pe wọn fipa ba eeyan laṣepọ wa nibi oju ara ọmọ yii.
AWIKONKO gbọ pe ọpọ igba ni Ṣẹgun ti fi oriṣirṣi nnkan tan ọmọ yii, to si maa n muu lọ sawọn agbegbe tẹnikẹni ko ti ni i ri wọn, iyẹn nibi to ti maa n lo anfaani ilera ara rẹ lati maa ko ibasun fun un.
Ki ọsẹ yii to o jalẹ ni Ṣẹgun yoo foju ba ile ẹjọ, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
No comments:
Post a Comment