Eegun Eṣuleke da ipade akanṣe adura fun Naijiria ru l'Oṣogbo, wọn tun yinbọn pa olori ẹsin Islam n'Iwo danu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 28, 2021

Eegun Eṣuleke da ipade akanṣe adura fun Naijiria ru l'Oṣogbo, wọn tun yinbọn pa olori ẹsin Islam n'Iwo danu


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Ọjọ buruku eṣu gbomimu lọjọ Aiku, Sannde ana yii jẹ niluu Oṣogbo, nigba ti wọn sọ pe awọn eleegun da akanṣe ipade adura tawọn musulumi gbe kalẹ lati fi gbadura fun orileede Naijiria ru.
 
Awọn mejila la gbọ pe wọn fara gbọta, ti ẹni kan si gbabẹ sọda sọrun alakeji, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ.
 
 
AWIKONKO gbọ pe ni nnkan bi aago meji aabọ ọsan niṣẹlẹ kayeefi naa waye, lasiko ti wọn lawọn musulumi n gbadura lọwọ ninu mọṣalaṣi apapọ ti Kamọrudeen {Kamọrundeen Central Mosque}, to wa ni Oluọdẹ Aranyin, Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun.
 
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe awọn eleegun naa ti gbe Eegun wọn kọja niwaju mọṣalaṣi naa, ti wọn si lawọn ọlọpaa tẹle wọn lẹyin fun aabo.
 
Ko pẹ la tun gbọ pe wọn pada, ti wọn si dabọmn bo awọn to wa ninu mọṣalaṣi naa lojiji. Eyi gan an lo mu ki ọrọ naa di pẹntuka, ti awọn eeyan si sa asala fun ẹmi ara wọn.
 
 
Pupọ awọn ti ibọn naa ba la gbọ pe ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtadinlogun lọ, ti gbogbo wọn si ti wa lọsibitu kaakiri, nibi ti wọn ti n gba itọju.
 
Lara awọn to faragbọta ni Abduljẹleel Ali, ọmọ ọdun mejila, ti ibọn ba laya ati ẹsẹ; Adebayọ Awolesin, ọmọ ọdun mẹẹdogun ti ibọn ba lapa; Taofeeq Fatai, ọmọ ọdun mẹtadinlogun ati Maliq Abdukabir, ọmọ ọdun mẹtadinlogun, ni wọn n gba itọju lọwọ ni ọsibitu ijọba tilu Oṣogbo, iyẹn, Osun State University Teaching Hospital.
 
Yatọ si awọn to faragbọta wọnyi, a tun gbọ pe ṣe ni wọn fọ gbogbo ferese atawọn dukia mọṣalaṣi naa danu, koda ti mọto ayọkẹlẹ Toyota Camry kan naa tun farakaaṣa.
 
Ẹgbẹ musulumi kan ti wọn pe ni Kamorudeen Islamic Society of Nigeria ni wọn ṣe agbekalẹ akanṣe eto adura naa, ti awọn ẹlẹsin musulumi kaakiri ipinlẹ naa si wa lati gbadura fun Naijiria, ilẹ abinibi wọn.
 
Ọkan lara awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Ọgbẹni Isiaka Ajagbe, ẹni ọdun mẹtadinlogoji nigba to n ṣalaye nnkan ti oju rẹ ri, o ni ọkunrin kan to n jẹ Kayọde Eṣuleke lo lewaju awọn eleegun naa lati da wahala ọhun silẹ.
 
 
Imaamu mọṣalaṣi naa, Kazeem Yunus fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si tun fi ye wa pe olori ẹgbẹ naa niluu Iwo, Mọshood Salawudeen naa faragbọta, to si ni oju ọna ọsibitu lo ku si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI