Gbegede gbina: AbdulRazaq tu aṣiri bi wahala ẹgbẹ oṣelu APC ṣe bẹrẹ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 28, 2021

Gbegede gbina: AbdulRazaq tu aṣiri bi wahala ẹgbẹ oṣelu APC ṣe bẹrẹ ni Kwara


Gomina
AbdulRahman AbdulRazaq ti tu awọn aṣiri nla tẹnikẹni ko gbọ ri nipa nnkan to bi wahala to n fojoojumọ ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ naa, ati idi ti ko fi da awọn eto kan ti wọn n ṣe ninu ẹgbẹ naa.
 
Nibi ayẹyẹ ifilọlẹ iwe kan ti wọn pe ni 'O TO GẸ', ni Ọgbẹni Kayọde Alabi to jẹ igbakeji rẹ ti tu pẹrẹpẹẹrẹ ọrọ naa kalẹ fawọn eeyan.
 
AbdulRazaq sọ pe aifẹ sọrọ oun tẹlẹ, ki i ṣe pe boya oun n bẹru, ṣugbọn ki alaafia le tubọ maa jọba lo jẹ koun maa panumọ, ṣugbọn to sọ pe oun ko le ṣai ma ṣi oju awọn eeyan sawọn nnkan to da wahala silẹ ninu ẹgbẹ naa titi doni.

O ṣalaye siwaju si i wi pe awọn kan lọọ gba owo lọwọ awọn ẹlẹyinju aanu lati fi ran eto idibo to gbe oun wọle lọwọ, ṣugbọn to lawọn eeyan naa ko gbe owo yii kalẹ. Lẹyin eyi lo tun sọ pe ẹgbẹ naa gbe eto kan toun ko mọ nipa rẹ kalẹ, ti wọn si koun wa maa na owo lee lori, eyi to loun ko gba fun wọn. O wa jẹ ko di mimọ pe nnkan to ba wọn lẹru ni bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe jawe olubori lẹẹkeji.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Mo ni lati jẹ kawọn eeyan mọ ipilẹ ohun to da wahala ẹgbẹ silẹ. Mi o bẹrẹ lẹyin idibo tabi ibura. Mo ni alaafia lati sọ pe gbogbo awọn ti wọn lawọn ni ẹgbẹ yii ni wọn kọ mi silẹ patapata, ko to di pe Aarẹ Buhari jawe olubori. Eyi lo ṣi oye wọn si ohun to le ṣẹlẹ, ti gbogbo wọn si pada wa sile.
 
"Bayii ni itan naa ṣe bẹrẹ. Ni kete lẹyin idibo abẹle, ẹgbẹ sọ fun mi pe awọn ti gbe eto bi ipolongo idibo yoo ṣe lọ kalẹ. Ko sẹni to sọ eyi fun mi ko to di pe wọn gbe igbesẹ naa, bo tilẹ jẹ pe emi ni oludije sipo gomina. Wọn sọ fun mi pe ki n maa na owo sori eto ipolongo idibo tawọn gbe kalẹ ti mi o mọ nnkankan nipa ẹ yii. Mi o gba si wọn lẹnu.
 
 
 
"Mo ni ki wọn jẹ ki n maa lewaju eto temi naa ti gbe kalẹ fun ipolongo idibo niwọnba ti agbara mi ka. O ṣi wa ni akọsilẹ bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii wi pe ẹgbẹ ko yọju sawọn ibi ti mo ti lọ ṣe ipolongo idibo mi.
 
"Awọn oloye ẹgbẹ tẹle aṣẹ wi pe wọn ko gbọdọ yọju sawọn ibi ti mo ti lọ ṣe ipolongo idibo. Ninu wọn lo le jẹri sawọn nnkan ti mo n sọ yii. Mo lọ kaakiri ijọba ibilẹ Ariwa Kwara lai si oloye ẹgbẹ kankan to tẹle mi.
 
"Nigba ti Aarẹ Buhari wọle ni pupọ ninu wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ si i fi ọgbọọgbọn darapọ mọ mi, iyẹn nigba to ti han si wọn pe awọn ara Kwara ti ṣetan lati dibo fun wa.
 
"Emi o mọ nipa eto oṣelu awaarawa, ti oludije ko ni le ṣe agbekalẹ eto ipolongo idibo rẹ. O tun jẹ ki nnkan buru nigba awọn oloye ati agbaagba ẹgbẹ ko yọju sibi ipolongo idibo ti mo ṣe, nitori pe mi o gba lati jẹ ki wọn paṣẹ fun mi.
 
"Gbogbo ọmọ ipinlẹ Kwara ni wọn ṣe wahala ati idaamu lori 'Otogẹ', ti wọn si ṣiṣẹ takuntakun ṣaaju idibo ọdun 2019 lọna ti wọn mọ.
 
"Bakan naa, ẹ gba mi laaye lati n ṣalaye lori ohun tawọn kan n sọ itan le lori nita. Ariwo 'Otogẹ', ati bi a ṣe mu ọrọ naa ko ṣẹyin awọn iwadii ti mo ṣe lẹyin idibo abẹle to waye loṣu kẹwaa, ọdun 2018. Bi ẹnikẹni ba sọ pe oun loun ṣagbekalẹ 'Otogẹ', yoo jẹ Hook Nigeria, ileeṣẹ eleto ikansira-ẹni kan. Ọkan lara awọn to ni ni Toyyib, Ọmọọba ni Guusu Kwara.
 
"Mo ti ṣe ipade loriṣiriṣi pẹlu awọn ileeṣẹ to n gbeeyan larugẹ 'PR Outfits', ṣugbọn mo ri i pe ti wọn lo tẹ mi lọrun, nitori to sọ nnkan tawọn eeyan nilo nipinlẹ Kwara. Nnkan ti a si fi ṣe ipolongo idibo wa niyẹn. Orukọ gbayii debi pe awọn ọlọkada, oni-tirela atawọn ọlọja kaakiri n pariwo rẹ kiri. Si ogo Ọlọrun, a dupẹ lọwọ awọn ara Kwara fun ipa ti wọn ko."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI