Gbagede Aṣa ati Igbafẹ Esie, ibi apewaawo ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin - Aṣoju ilẹ Faranse silẹ Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 4, 2021

Gbagede Aṣa ati Igbafẹ Esie, ibi apewaawo ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin - Aṣoju ilẹ Faranse silẹ Naijiria


Jerome Pasquire to jẹ aṣoju ilẹ Faranse si orilẹede Naijiria l'Ọjọbọ ti i ṣe Tọsidee ana ti gbe oṣuba kare fun ipinlẹ Kwara lori gbagede aṣa ati igbafẹ wọn ti wọn pe ni Esie Museum, to si ni ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ninu awọn eyi toun ti ri kaakiri agbaye.
 
Ọkunrin naa sọ pe awọn nnkan toun foju ri ninu ile aṣa ati igbafẹ naa jọ oun loju gidi, ati pe oun ko ti i ba iru ibi igbafẹ bẹẹ pade ri latigba toun ti n kaakiri lati bi ọdun meloo kan sẹyin.
 
Siwaju si i ninu ọrọ rẹ lo sọ pe "Inu mi dun lati wa nibi. Mi o ti i gbọ nipa ile aṣa ati igbafẹ Esie ri laye mi. O jẹ nnkan iwuri lati tun ṣalabapade ẹ. Ile aṣa ati igbafẹ to ṣee figagbaga si ti agbaye ni, to si yẹ ki gbogbo agbaye mọ nipa rẹ."
 
"O di dandan ki n sọ fun awọn alaṣẹ wa nilẹ Faranse lati ṣe abẹwo sibi yii lati le tubọ kẹkọọ siwaju si i nipa awọn nnkan ti mo ba pade, nitori pe yoo wulo fun itan, arọba, ohun aṣa ati ohun yiya ti ibilẹ."
 
Asiko ti ijọba ipinlẹ naa ṣi oju ọna to lọ si gbagede Esie naa to w ni ijọba ibilẹ Irẹpọdun ni Jerome sọrọ yii, iyẹn l'Ọjọru-Wẹsidee.
 
"Pẹlu oju ọna tuntun ti ijọba ṣẹṣẹ ṣe yii, yoo fun awọn araalu, onile ati alejo lanfaani lati maa wa si ibi yii daadaa, ki wọn si wa a gbadun ara wọn. O da yatọ ni agbegbe yii, bẹẹ si naa lo ri lagbaye. O tun le jẹ ibi ti gbogbo agbaye yoo maa wa wo, ti yoo si maa mu owo gidi wa fun ipinlẹ Kwara."
 
Yatọ si eyi, Jerome tun gbe oṣuba kare fun Gomina ipinlẹ Kwara lori awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to ti ṣe laaarin ọdun meji to de ipo naa, eyi to fi n sọ pe aṣoju rere ni Gomina AbdulRazaq, to si tun jẹ ko di mimọ pe aritọkasi rere lo jẹ fawọn to n bọ lẹyin rẹ.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI