Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede sita wi pe ohun ti gbẹsẹle ọkada ti ko din ni aadọrin lori ẹsun wi pe wọn ko ni nọmba idanimọ.
Ana ti i ṣe Tusidee ni ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ naa jade.
Wọn ni ko si idi meji ti wọn fi gbẹsẹle awọn ọkada bi ko ṣe ti wahala tawọn ọlọkada n fa lẹnu ọjọ mẹta kan sẹyin, nibi ti wọn ti n ba dukia awọn araalu jẹ.
Ana naa la gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ ofin lati maa mu awọn ọkada ti ko ba ni nọmba idanimọ kaakiri ipinlẹ ogun, eyi ti wọn bẹrẹ niluu Abẹokuta, ti wọn si gba oriṣiriṣi ọkada silẹ.
Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti wa a jẹ ko di mimọ pe bawọn ti wọn gba ọkada lọwọ wọn ba le ko iwe ọkada wọn pẹlu nọmba idanimọ ọkada wọn wa, anfaani wa wi pe wọn yoo gba ọkada wọn pada, ṣugbọn bi wọn ko ba ri iwe ko silẹ, wọn yoo gba a silẹ.
No comments:
Post a Comment