Minisita fun ọrọ aṣa ati iroyin lorilẹede yii, Alaaji Lai Mohammed ti sọ pe ìdàgbàsókè to ti de ba ipinlẹ Kwara latigba ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gba ijọba kan ni ẹlẹgbẹ, ati pe wọn ko ti i ni iru Gómìnà bi ọkunrin naa latigba ti wọn ti bẹrẹ ijọba awaarawa.
Lai Mohammed ni ọna ti AbdulRazaq n gba ṣe awọn akanṣe iṣẹ nipinlẹ naa jẹ eyi to n ya awọn araalu lẹnu nitori pe iru ìdàgbàsókè bẹẹ ko ṣẹlẹ ri i.
Ninu atẹjade to fi n ki AbdulRazaq ku oriire awọn àṣeyọrí ti ko ni ẹlẹgbẹ lo ti sọ pe ki í ṣe pẹlú ipo tàwọn jọ wa sira wọn, oun ko le ṣalai ma sọ otitọ tó yẹ nitori pe aarun ojú yatọ si aarun imu.
Siwaju si i lo sọ pe pẹlu bawọn ṣe maa n ni gbolohun asọ to, sibẹ AbdulRazaq ko fi ijọba rẹ ṣe ti ẹlẹyamẹya, tori pe o tun ṣiṣẹ ìdàgbàsókè de agbegbe Oro to wa ni ijọba ibilẹ toun ti jade wa, eyi to ni awokọṣe rere ni gomina naa.
No comments:
Post a Comment