Ẹgbẹ oṣelu Action Alliance ipinlẹ Ogun fawọn oludije kalẹ fun ibo ijọba ibilẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 3, 2021

Ẹgbẹ oṣelu Action Alliance ipinlẹ Ogun fawọn oludije kalẹ fun ibo ijọba ibilẹ


Lọsan-an, onii lẹgbẹ oṣelu Action Alliance, tipinlẹ Ogun fawọn oludije kalẹ fun ipo alaga ati kanselọ fun ti ibo ijọba ibilẹ to n bọ ninu oṣu keje ọdun yii.

Nibi eto ọhun to waye ni ootẹli Tyme Out, to wa lẹgbẹ ileepo Sandop, Olomoore, niluu Abẹokuta, lawọn ọmọ ẹgbẹ naa ti parapọ yan awọn ti yoo dije lawọn ijọba ibilẹ ọhun,

Ninu ọrọ Ọgbẹni Tunji Akọni, to jẹ kọmiṣanna akọkọ, nileeṣe to n ri si eto ibo ọhun iyẹn OGSIEC, lo ti fi idunnu ẹ han lori bawọn ọmọ ẹgbẹ AA ṣe wa ni iṣọkan fun ibo pamari ti wọn ṣe laaarin wọn.


Bẹẹ lo tun mu daju fun wọn lorukọ alaga igbimọ to n ṣeto ibo ọhun nipinlẹ Ogun, Iyẹn Ọgbẹni Babatunde Akọni pe nirọwọ-rọsẹ ni ibo naa yoo waye ati pe ẹni tawọn araalu ba dibo fun lawọn yoo fa ọwọ ẹ soke.

Bẹẹ lo tun fikun ninu ọrọ ẹ pe ko ni si aye fun magomago lakooko ti ibo ọhun ba waye, o wa ni kawọn oloṣelu atawọn araalu fọkanbalẹ nitori pe awọn ti ṣetan lati jẹ ki gbogbo ẹ lọ, bo ṣe yẹ, laini wahala kankan ninu.

Akọni tun wa rọ awọn ẹgbẹ oṣelu AA lati tẹle awọn ilana ti ajọ to n ṣeto ibo yii la kalẹ fawọn oludije wọn, ki wọn si ri i pe wọn to gbangba sun lọyẹ.

Nigba toun sọrọ nibi eto naa, Ọgbẹni Abayọmi Sanyaolu, to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Ogun, fi ẹmi imoore ẹ han si awọn to wa ṣoju ajọ OGSIEC, o ni eyi fi awọn lọkanbalẹ pe wọn yoo ṣe nnkan tawọn ẹgbẹ oṣelu atawọn araalu n fẹ lakooko ibo ọhun.

Bẹẹ lo tun gboriyin fun Ọgbẹni Tunji Akọni, nipa bi wọn ṣe n ṣe bi baba ati ọmọ latigba ti awọn ti bẹrẹ eto yii. O ni ko sigba toun  de ọfiisi wọn lati beeere nnkan to ba ruju lori ibo yii, ti wọn ko ni da oun lohun.


O wa rọ wọn lati ma ṣe jẹ ki igbẹkẹle tawọn oloṣelu atawọn araalu ni ninu wọn fun ibo ijọba ibilẹ yii ko ja si asan. Bẹẹ lo ni ẹgbẹ oṣelu AA tipinlẹ Ogun naa ti ṣetan lati tẹle gbogbo ilana ti wọn ba la silẹ.

Oloye Dapọ Adeyẹmi to jẹ olori wọn ninu ẹgbẹ oṣelu AA, nipinlẹ Ogun naa tun dupẹ pupọ lori bi eto ọhun ṣe kẹsẹ jari, o wa sọ pẹlu igbagbọ pe awọn yoo gbegba oroke ninu ibo ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI