Laja Majẹkodunmi ko to ipo olori ṣe - Awọn oludije alaga ijọba ibilẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 15, 2021

Laja Majẹkodunmi ko to ipo olori ṣe - Awọn oludije alaga ijọba ibilẹ


Awọn oludije mẹsan-an sipo alaga ijọba ibilẹ ni Abẹokuta South, nipinlẹ Ogun, ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti ẹni ti wọn fa kalẹ gẹgẹ bi oludije fẹgbẹ oṣelu APC, nijọba ibilẹ naa kalẹ, Ọgbẹni Laja Majẹkodunmi, bi ẹni ti ko ni lakaaye, ti ko si to ẹni ti wọn gbe gbe ipo olori fun.

Ninu atẹjade tawọn oludije alaga ijọba ibilẹ mẹsan-an naa fọwọ si, awọn naa ni Olujimi Adekunle Desmond, Enilọlobọ Toyọsi, Omitoogun Muiz, Kelani Taiwo Lukman ati Dare Olumide.

Awọn yooku ni Adedayọ Ọkanlawọn Akintoye, Agbẹjọro Ayọdeji Kẹhinde, Mustapha Kọdaolu Ọlajide ati Saheed Balogun. 

Wọn ni ọrọ ti ọkunrin naa sọ yii ko tọ si lẹnu to jẹ pe akoko ti wọn n wa iyanju sawọn wahala ninu ẹgbẹ naa.

Ninu Fọnran ọrọ ti oludije ọhun, Laja Majẹkodunmi, sọ to tẹ wa lọwọ lo ti sọ pe "Lẹẹkan mo sọ fun yin pe mo lọ sibi ifọrọwerọ ori redio, ibẹ ni mo ti n bọ.ija ko ti i pari, awa ro pe o ti pari ni, nitori awọn ibeere ti wọn ti wọle, ija ko ti i pari.

‘’Awa jẹ ko ye wọn pe a ju wọn lọ, ijakadi kọ. Mo jẹ ko ye wọn pe ẹni ti wọn n sọrọ ẹ, Alaaji Farouq Akintunde, ẹgbọn lo jẹ si mi. Mo dẹ gbe fun un pe ka ni awọn ni wọn ma ba wa jẹ nibẹ ni, awọn ika abuku ti wọn fi kan awọn olori wa, awaawi ni, ko si nnkan to jọ.’

‘’Mo jẹ ko ye wọn wi pe awọn aṣaaju wa, wọn ni orukọ rere tawọn kan ko ni, wọn b mi leeere pe ki lo de ti wọn fi mu mi, mo ni ko ye mi, boya iwa, wọn tun ni ki a maa ṣepe lori afẹfẹ. Oludari eto sọ pe ko ba ilana ofin redio mu, mo wa da oludari eto naa lohun pe ko fi wọn silẹ, ẹni ta a ba na lara n ta.’’

Nigba tawọn oludije mẹsan an naa sọrọ, wọn ni bigba teeyan tun da pẹtiroolu sina lawọn ka ọrọ ẹ si ati pe ẹni to ba lọgbọn to loye ko yẹ kiru ẹ maa jade lẹnu ẹ. 

Wọn lo yẹ kijọba tete paarọ ọkunrin yii ko ma ba di pe yoo maa boju ijọba ibilẹ naa jẹ to ba depo.

Wọn ni ẹni ti ko ti i depo to fẹẹ maa tabuku awọn kan, to ni ija ko ti i pari ta ni ko mọ pe to depo awọn onitọhun ni yoo kọkọ kọju ija si kaka ko gbajumọ bi irẹpọ ati alaafia yoo ṣejọba.

Wọn wa ro awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ki wọn ya tete wa nnkan ṣe si, ki ọrọ to ba jẹ patapata

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI