Mo fẹẹ di gbajugbaja adigunjale bi i Oyenusi, Ṣina Rambo lo jẹ ki n bẹrẹ iṣẹ ole lati ọmọ ọdun meje - Gbenga Kikiowo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 25, 2021

Mo fẹẹ di gbajugbaja adigunjale bi i Oyenusi, Ṣina Rambo lo jẹ ki n bẹrẹ iṣẹ ole lati ọmọ ọdun meje - Gbenga Kikiowo


Ọrọ buruku toun tẹrin gba a leleyi o. Nibi tọpọ awọn eeyan ti n ronu wi pe kawọn di oloriire, ki wọn di adari laye, ironu lati di gbajugbaja adigunjale ni Gbenga Kikiowo, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn n ro, ko to di pe ọwọ tẹ ẹ.
 
Laipẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo tẹ Gbenga lagbegbe Oke-Aro niluu Akurẹ. Oun pẹlu Aladeloye Tọpẹ lọwọ jọ tẹ lọjọ naa. Awọn mejeeji la gbọ pe wọn ko niṣẹ mi in ti wọn n ṣe ju iṣẹ adigunjale lọ.
 
Nigba tawọn ọlọpaa n foju rẹ han fawọn akọroyin, Gbenga sọ pe ko si nnkan meji to jẹ koun maa jale, bi ko ṣe lati di gbajugbagba adigunjale bi i Iṣọla Oyenusi, Ṣina Rambọ ati Mufu Olooṣa Oko lọ.
 
O ni ọna kan ṣoṣo toun mọ, ti orukọ oun le fi rinlẹ daadaa ni lati maa jale kaakiri agbaye, tawọn eeyan yoo si maa pariwo orukọ oun lọtun ati losi.
 
O ni ọmọ ọdun meje loun wa nigba toun bẹrẹ iṣẹ ole jija, ati pe awọn obi oun loun maa n ja lole nigba naa, ko to di pe oun jade sita lati maa lọ jale.
 
Siwaju si i lo lawọn obi oun gbiyanju lati yọ ole naa kuro loju oun,. ṣugbọn to ni ko ṣe e ṣe fun wọn. O sọ siwaju pe iṣẹ babalawo ti baba oun yan laayo ni wọn fẹẹ fi gba ole naa kuro lọwọ oun, ṣugbọn to sọ pe pabo ni gbogbo rẹ ja si.
 
O loun ti lọ siluu Ghana lati lọ jale, igba to ya lo ko awọn ti wọn jọ n jale ni Ghana wa si Naijiria lati le ji wọn tun ni iriri nipa bi wọn ṣe n jale nibi.
 
Ẹẹmẹta ọtọọtọ ni Gbenga sọ pe ọwọ ti tẹ oun, toun si ti lọ sẹwọn laimọye igba, o loun ti lọ ẹwọn ọdun mẹrin, ṣugbọn toun tun jade nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI