Tirela Dangote tun tẹ akẹkọọ girama kan pa n'Ilaro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, June 25, 2021

Tirela Dangote tun tẹ akẹkọọ girama kan pa n'Ilaro


Tirela ileeṣẹ Dangote tun ti tẹ akẹkọọ kan pa niluu Ilaro lonii ti i ṣe Furaidee.

Ohun ta a gbọ pe ni ṣe ni tirela naa kuro loju ọna rẹ, to si lọọ gba akẹọọ ileewe girama nibi ti wọn duro si.

Pẹlu ibinu lawọn to wa nibẹ fi lu gbogbo gilaasi tirela naa fọ danu, ti wọn si tun fẹẹ dana sun un, ṣugbọn tawọn ẹlẹyinju aanu tete da si i.

A gbọ pe awakọ tirela yii ko duro rara, wọn ni ṣe lo na papa bora bo ṣe ri i pe oun ti paayan.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI