Nitori ofin irinna mẹrindinlogoji tijọba Eko gbe jade, ibẹrubojo de bawọn awakọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, June 21, 2021

Nitori ofin irinna mẹrindinlogoji tijọba Eko gbe jade, ibẹrubojo de bawọn awakọ


Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe awọn ofin tuntun kalẹ fun gbogbo awọn awakọ patapata nipinlẹ naa, yala aladani ni tabi awọn eyi ti wọn fi n ṣiṣẹ akero kaakiri igboro.

Awọn ofin naa ta a gbọ pe ko din ni mẹrindinlogoji ni wọn ni ijiya wa fun lọtọọtọ, koda, tawọn to ba lufin naa tun ni anfaani lati san owo itanran.

1. Wiwa ọkọ lai ni iwe irinna awakọ {Driver’s license} – Wọn yoo gbẹsẹ le mọto naa.

2. Wiwa ọkọ lai ti i pe ọmọ ọdun mejidinlogun – N30,000.

3. Wiwa ọkọ pẹlu ayedederu iwe ọkọ – N30,000 tabi ẹwọn ọdun mẹta gbako.

4. Wiwa ọkọ pẹlu ayederu iwe mọto – Ẹwọn oṣu mẹfa pere.

5. Wiwa ọkọ pẹlu ayederu iwe irinna mọto  – Ẹwọn oṣu mẹfa pere.

6. Wiwa ọkọ lai ni iwe aṣẹ {road worthiness} – Wọn yoo gba mọto silẹ. 

7. Wiwa ọkọ nibi ti ko yẹ {Driving only yellow} – N80,000.
 
8. Wiwa ọkọ lai ni Hackey permit – Wọn yoo gbẹsẹ le mọto. 

9. Lai fi lẹ iwe Hackey permit sibi to yẹ – Wọn yoo gbẹsẹ le mọto.

10. Kabu Kabu lai ni iwe aṣẹ {permit} – Wọn yoo gbẹsẹ le mọto.
 

11. Aigbọran sawọn oṣiṣẹ LASTMA lẹnu – N30,000 tabi ki wọn gbẹsẹ le mọto

12. Jija ina to n dari ọkọ {traffic direction light} – Ẹwọn oṣu mẹta. 

13. Mimu siga/igbo lasiko ti a n wa ọkọ – N30,000 tabi ki wọn gbẹsẹ le mọto.

14. Ki koju ija sawọn oṣiṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ – N50,000 tabi ẹwọn oṣu mẹfa pere.

15. Wiwa ọkọ lai ni ina iwaju {full light} – N50,000. 

16. Wiwa ọkọ pẹlu taya ti ko dara – N30,000.

 17. Wiwa ọkọ lai ni taya pajawiri {spare tyre} – N30,000 

18. Wiwa ọkọ to n yọ eefin kiri – N30,000 

19. Wiwa ọkọ ti ko ni fire extinguisher – N30,000 

20. Gilaasi ọkọ to ti san {Broken windscreen} – N30,000 

21. Lilẹ ọra dudu mọ gilaasi mọto {tinted windscreen} – N30,000 

22. Jijẹun ati wiwa ọkọ pẹlu ọwọ kan ṣoṣo – Ẹwọn oṣu mẹta pere.

23. Wiwa ọkọ lọna ti ko tọ {One way driving} – Ẹwọn ọdun mẹta gbako.

24. Wiwa ọkọ lai lo bẹliiti – N30,000.

25. Wiwa awọn ọkọ akero ti ko ni ọda to yẹ – N50,000.

26. Awọn to n fi mọto ko eru lọ si ọna jinjin lai gba iwe aṣẹ {No car hire service permit} – akọkọ-20,000; ẹẹkeji-N30,000, ẹlẹẹkẹta- wọn yoo gbẹsẹ le mọto naa.

27. Gbigbe mọto sibi ti ko yẹ tabi ba ofin mu – akọkọ-N20,000; ẹẹkeji N30,000.

28. Wiwa mọto kọja loju ọna ti ko ba ofin mu {Vehicle crossing double yellow line/center line} – akọkọ-N20,000; ẹẹkeji-N30,000.

29. Diduro lori ibi ti ko ba ofin mu {Staying within the yellow junction box (offside rule)} – Akọkọ-N20,000; Ẹẹkeji-N30,000.

30. Aigbọran sofin ẹlẹsẹ {right of the way of pedestrian at zebra crossing} – Akọkọ-N20,000; Ẹẹkeji-N30,000 

31. Ai fi ọna silẹ lapa osi ni layipo {Failure to give to traffic on the left at a roundabout} – Akọkọ-N20,000; Ẹẹkeji-N30,000. 

32. Wiwa ọkọ tabi ọkada loju ọna ẹlẹsẹ – Wọn yoo gbẹsẹ le mọto.

33. Wiwa mọto pada sẹyin lopopona marosẹ tabi gbigbe mọto soju ọna ẹlẹsẹ – N50,000.

34. Ai tẹle ofin sunkẹrẹ-fakẹrẹ - N20,000.

35. Gbigbe ero tabi jija ero silẹ nibi ti ko yẹ - N50,000.

36. Wiwa ọkọ loju ọna BRT – N70,000.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI