Ọba Oludofian waja lojiji ni Kwara, ni Gomina ba fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, June 20, 2021

Ọba Oludofian waja lojiji ni Kwara, ni Gomina ba fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti ba gbogbo ọmọ ati olugbe ilu Idofian to wa nijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara kẹdun iku Kabiyesi wọn, Ọba
Zubair Agboọla Adeyẹye, Oluofian tilu Idofian to waja laipẹ yii.
 
AbdulRazaq ṣapejuwe iku Ọba na gẹgẹ bi adanu nla lasiko yii, to si ni gba gbogbo awọn eeyan ilu naa lamọran pe ki wọn ṣe ọkan akin.
 
Ọjọ Ẹti, Fridee, ọsẹ yii, ni wọn kede pe Ọba naa waja, to si ti lọọ darapọ mọ awọn baba-nla rẹ, lẹyin to ti lo ọdun mẹrindinlọgọta (56) lori itẹ.


AWIKONKO gbọ pe, Ọba Adeyẹye ni ọba to dagba ju lọ ninu gbogbo awọn ọba alaye to wa nipinlẹ Kwara, ko too di pe o dagbere faye.
 
Ninu oṣu karun un, ọdun (1965), lo gori apere baba to bi i lọmọ, to jọba ilu Idọfian, o papoda ni owurọ kutukutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfa, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI