Onyinyechi ree, arẹwa agbabọọlu fun Super Falcons to kuro ni Swizerland wa si Naijiria (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 16, 2021

Onyinyechi ree, arẹwa agbabọọlu fun Super Falcons to kuro ni Swizerland wa si Naijiria (Fọto)


Ọmọ ọdun mẹrinlelogun ni Onyinyechi Zogg, to n gba bọọlu fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu FC Zurich lorileede Swizerland tẹlẹ.

Laipẹ yii ni Onyinyechi to n di ọwọ ẹyin mu fun FC Zurich sọ pe yoo wu oun lati maa gba bọọlu fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu awọn obinrin agba, Super Falcons.

O loun fẹẹ fi FC Zurich silẹ lati wa gba bọọlu fun Naijiria nigba ti wọn pe e lati rọpo Onome Ebi.

Bo ṣe de sinu ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons lo ti pẹlu bawọn koju ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Reggae Girlz lati Jamaica.

Orileede Switzerland ni wọn bi Onyinyechi si, to si jẹ pe lati kekere lo ti fẹran ere bọọlu, eyi to ba a dagba.

Latigba ti wọn loo ti darapọ mọ Super Falcons ni wọn lo ti n fi idunnu rẹ han wi pe oun ri anfaani nla gba lati gbe ogo orileede baba oun ga.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI