Satide Ẹrẹbẹ: Oloye Bayọ Dayọ, agba oṣelu PDP nipinlẹ Ogun fẹẹ ṣayẹyẹ ọjọọbi ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 24, 2021

Satide Ẹrẹbẹ: Oloye Bayọ Dayọ, agba oṣelu PDP nipinlẹ Ogun fẹẹ ṣayẹyẹ ọjọọbi ẹ


Bo tilẹ jẹ pe Oloye Bayọ Dayọ, agba oṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinle Ogun, to tun jẹ alaga ẹgbẹ naa, ti sọ pe awọn ko fẹẹ pariwo, ṣugbọn o ti han daju pe lọjọ Abamẹta Satide, ọsẹ yii  ni yoo ṣayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹrindinlọgọrin.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ohun ti ọjọọbi ohun wa fun lati fi dupe lowo Olorun fun pe o da a si lati fi odun kan kun odun e ninu aye.

Idupe nikan la gbo pe okunrin agba oselu ohun fee fi se laaarin oun atawon ebi e. Ko si tun lo akoko naa lati fi toro emi gungun.

Odu ni Bayo Dayo lagbo oselu ki i saimo foloko, o si ti kopa to joju lati mu ki idagbasoke ba ipinle Ogun, paapaa ilu Ijebu-Igbo, ti okunrin naa ti wa.

Ohun ti won ni okunrin naa maa n wa ni ki alaafia, ife ati isokan joba nibi to ba wa, idi niyii ti ko se fi ya awon lenu nigba to fee gbejoba sile gege bi alaga fegbe oselu PDP, nipinle Ogun, to fi gba lati je ki egbe ohun pada sinu ogo ti won ti wa tele, eyi ti won fi dari ipinle ohun fodun mejo.

Gbogbo awon eeyan lo n ki Bayo Dayo ku oriire pelu adura pe yoo sopo odun laye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI