Twitter: Gbigbo aja ijọba Buhari ko le da ẹkun mi duro lailai - Fani-Kayọde - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, June 6, 2021

Twitter: Gbigbo aja ijọba Buhari ko le da ẹkun mi duro lailai - Fani-Kayọde


Minisita tẹlẹ ri fọrọ ọkọ ofurufu lorilẹede Naijiria, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde ti sọ pe gbigbo aja ijọba orilẹede Naijiria ti Aarẹ Muhammadu Buhari n ṣakoso rẹ ko le da ẹkun oun duro.
 
Laipẹ yii ni nijọba apapọ kede wi pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ wi pe o tun lo ikanni ayelujara agbẹyẹfo ti wọn pe ni Twitter yoo foju winna ofin, ati pe ẹnikẹni lorilẹede yii ko gbọdọ loo mọ.
 
Fani-Kayọde laaarọ oni sọ pe oun ti lọ sori ikanni Twitter naa, oun si ti kọ ọrọ sibẹ, nitori naa o loun n duro de eni ti yoo wa lati mu oun, tabi fi oun jofin gẹgẹ bi wọn ṣe n sọ.

Eyii ni nnkan ti Fẹmi Fani-Kayọde kọ sori ikanni fesibuuku rẹ:No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI