Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ baba agbalagba ẹni ọdun mọkanlelọgọta kan lori bo ṣe lu ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mọkanla lori fọ danu.
Adugbo kan to wa lagbegbe Ikosi ni Ketu, ipinlẹ Eko niṣẹlẹ naa ti waye lọsẹ to n pari lọ yii.
Awọn ara adugbo la gbọ pe wọn lọ fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ijọba to n ri si ẹtọ araalu nileeṣẹ to n ri sọrọ ofin, iyẹn Directorate of Citizens Rights, Lagos State Ministry of Justice.
AWIKONKO gbọ pe ki i ṣe akọkọ ree ti baba agbalagba naa yoo maa fiya jẹ ọmọ rẹ yii ati aburo rẹ latigba ti mama ti ku, paapaa nigba ti baba naa fẹ iyawo tuntun.
Wọn ni ṣe lawọn ara adugbo mu ọrọ naa mọra, ṣugbọn eyi ti baba naa ṣe gbẹyin yii lo bi wọn ninu, ti wọn si lọọ fọrọ rẹ to awọn alaṣẹ leti.
Awọn alaṣẹ naa la gbọ pe wọn fa baba arugbo yii le awọn ọlọpaa lọwọ.
No comments:
Post a Comment