Wahala ti wọn n ba Arẹgbẹṣọla fa ni Ọṣun lo n da ọpọlọ ẹ laamu - Ṣina Akinpẹlu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 10, 2021

Wahala ti wọn n ba Arẹgbẹṣọla fa ni Ọṣun lo n da ọpọlọ ẹ laamu - Ṣina Akinpẹlu


Ṣina Akinpẹlu, odu ni ki i saimọ foloko bi wọn ba sọrọ nipa ajijajagba, oun ni alukoro fẹgbẹ Oodun People Congress, OPC New Era, laipẹ yii lo ba oniroyin wa sọrọ nipa ibi ti nnkan de paapaa lori wahala to waye niluu Igangan, nipinlẹ Ọyọ. Ohun to ba wa sọ niyii.

Kin ni ẹ ri si ọrọ ti Arẹgbẹsọla sọ lori ẹyin tẹ ẹ fẹ da ominira Yoruba silẹ, to ni oponu niyin?
Bi ẹgbọn ba sọ bẹẹ, o tumọ si pe nnkan ti wọn jẹ ko jẹ ki wọn gbọn. Ki wọn to mọ ẹni to n jẹ Arẹgbẹ nigba ti wọn wa ni Aiportt Hotel, gẹgẹ bi Technician, Ko sẹni to mọ wọn nigba taa n ja fun ijọba tiwa-n-tiwa,ti June 12 de, ni wọn to mọ wọn.

Bi wọn ba ni ko ri bẹẹ ki wọn jade, ki wọn sọ igba taye mọ wọn. June !2 lo fa Arẹgbẹsọla, bi a ba wa n sọrọ nipa June 12, a o ma sọrọ nipn nnkan to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii.

Bi a ba tun wa sọrọ nipa Arẹgbẹ, a tun sọ pe ọga wa ni wọn,bi wọn ba wa roo pe awọn ti debi ti wọn fẹẹ de, nitori pe wọn ti di minisita, ni Naijiria, niluu ti ko lorukọ.

Kin ni itumọ Naijiria, ta lo sọ wa ni Naijiria, awọn ilu to wa leti bebe ọya.Ilu ti ko leke, bawo wa ni Buọda ṣe waa maa la ẹnu, gẹgẹ bi ọmọluabi, bawo ni wọn yoo to wa sọ pe awa taa n ja fun ominira ọmọ Yoruba pe oponu ni wa, o ku diẹ kaato, ede ti ko dara ni.

O dabi ẹni pe ọrọ ẹni ti wọn ba n fa wahala ni Ọṣun, lo fẹ maa da ọpọlọ wọn laamu. Ti iru Arẹgbẹ to jere June 12 ba wa n sọ iru ẹ jade, o dabi ẹni pe awọn gan-an ni nnkan ta si lọpọlọ.

Njẹ ẹ ni gbagbọ ninu ki Yoruba di ominira?
Mo nigbagbọ ninu ẹ to pọ, ẹni ti ko ba ti nigbagbọ, ko nigbagbọ ninu Awolọwọ ni. Nitori bi ẹ ba ranti nnkan to gbe Awolọwọ lọ sọgba ẹwọn lọjọsi, Ọrọ nipa ilẹ Yoruba ni, ki wọn maa di ero ẹyin ni.

Bi ẹ ba wa wo orin ogo ilẹ wa, o sọ fun wa pe aṣiwaju ni wa, pe ka dide, ọrọ naa lo dide lọwọlọwọ bayii. Bi Arẹgbẹ ṣe lo n ka iwe to ko ju HND lọ, Baba to jẹ olori wa nilẹ Yoruba lakooko yii, ọjọgbọn ni, Baba Bamji Akintoye. Arẹgbẹ ko gba oye ọjọgbọn ri, ko ma jẹ kaa sọrọ o,ẹni to sọ ọ deeyan, iwe meloo lo ka. Ki ẹgbọn ma sọrọ si wa mọ o. Wọn lo tun sọ pe nnkan ti wọn pe ni Amọtẹkun, wọn fi akoko wọn sofo ni.

Ṣe o ti gbagbe pe iru nnkan bẹẹ lo fẹẹ ṣe nigba tiẹ, ti ko rii ṣe. Oun naa lo kọkọ fẹ da ominira Yoruba silẹ o.
 
To da Dynastic silẹ ni Ọṣun, to ni a o ma kọ ẹkọ, lati ma fi karate bawọn Fulani ja, ti wọn ba koju wọn. Nitori ko ṣe aṣeyọri ẹ lo fi ni awa taa si n gbeja lọ, to ti gbagbe pe inu ẹ ni wọn wa ati Tinubu to jẹ ọga wọn. Ohun to kan ni pe ki Arẹgbẹ ma jẹ kaa kọlu, ẹni ti ko yẹ kaa kọlu, nitori baba wa ni. Nitori ọrọ abuku lo sọ si orileede Yoruba.

Kin ni ẹ ri si wahala to waye niluu Igangan?
Ṣe ẹ ri ọrọ ti Igangan, mo kan fi akoko yii rọ Arẹgbẹ atawọn ọmọ Yoruba to wa nile igbimọ aṣofin, atawọn Yoruba to wa kaakiri ti wọn wa nijọba yii paapaa julọ Igbakeji Aarẹ orileede yii, Yẹmi Ọṣinbajo, lọwọlọwọ bayii, bi wọn ko ba ṣe nnkan to tọ, ọmọ Yoruba yoo mu ofin lọwọ ara ẹ.OPC lemi, ti wọn ko ba ṣe oun tootọ laaarin akoko perete ọmọ Yoruba yoo mofin lọwọ ara ẹ.

A ti ri lakooko yii pe ko sofin to mu Fulani, ko sofin to mu awọn to wa loke, emi si n sọ fun ọpọlọpọ awọn eeyan wa pe awọn tileeṣẹ aarẹ lo n sọrọ.Mi o ro pe a ni nnkan to n jẹ aarẹ lorileede yii, to ba ṣe pe lootọ ni o wa ko da si ọrọ Igangan, bi ko ba ti da si, laaarin akoko perete Yoruba yoo gbeja ara wọn ja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI