Kamaldeen, ọmọ Alaaji Akewuṣọla kẹkọọ-gboye nile ẹkọ Keu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 9, 2021

Kamaldeen, ọmọ Alaaji Akewuṣọla kẹkọọ-gboye nile ẹkọ Keu


Ọlaide Ọṣinuga, Eko

Ẹsẹ ko gbero nile ẹkọ Keu ti Markaz, iyẹn Markaz Arabic School to wa niluu Agege, ipinlẹ Eko lọsẹ to kọja yii nigba ti ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja Alaaji Ganiy Ajibade, ẹni tọpọ awọn ololufẹ ẹ mọ si Akewusola se ayẹyẹ ikẹkọọ-gboye ẹ.

Bawọn ololufẹ Alaaji Akewuṣọla ṣe peju sibi ayẹyẹ yii naa lawọn afẹnifẹre ko gbẹyin nibẹ lati bu ọla ati ẹyẹ fun ọmọ gbajugbaja ọkunrin to n fi gbogbo nnkan to ni naa gbe ogo ẹsin Isilaamu ga.
 
Ọjọ Satide ọsẹ to kọja yii ni ayẹyẹ nla naa waye, ti a si gbọ pe titi di asiko ta a pari iroyin yii lawọn eeyan ṣi fi n royin bi ayẹyẹ naa ṣe lọ. 
 
Kamaldeen Bọlaji Ajibade lorukọ ọmọ Akewuṣọla naa to kẹkọọ-gboye yii, nibi to ti gba oriṣiriṣi ẹbun manigbagbe. 
 
Ayẹyẹ Hafiat Shahadah naa to bẹrẹ ni nnkan bi aago mejila ọsan ọjọ naa ni wọn loo tun ku fun oniruuru awọn agba oniwaasi agbaye.
 
Nigba to n dupẹ lọwọ Allah atawọn alejo rẹ, Alaaji Akewuṣọla sọ pe ohun to dara ni lati fun awọn ọmọ ni ẹko to ye kooro, paapaa ni ilana ẹsin, to si loun ko lẹ ṣai dupẹ lọwọ to dide wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI