Ìja Jóṣúà ati Usyk fẹ́ẹ́ gbọ̀nà àrà yọ lọ́jọ́ karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹsàn-án - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, July 21, 2021

Ìja Jóṣúà ati Usyk fẹ́ẹ́ gbọ̀nà àrà yọ lọ́jọ́ karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹsàn-án


Igbaradi nla lo ti bẹrẹ laaarin awọn abẹṣẹku-bi-ojo agbaye nni, Anthony Joshua ati Oleksandr Usyk ti wọn fẹẹ koju ara wọn lọjọ karundinlọgbọn, ọsu kẹsan-an, ọdun ti a wa yii.
 
Anthony Joshua lo n di bẹliti agbara ti WBA, IBF ati WBO dani lati bi oṣu meloo kan sẹyin, lẹyin to lu pupọ awọn alagbara abẹṣẹku-biojo agbaye loriṣiriṣi.
 
Papa iṣere ti Tottenham Hotspur to wa niluu London la gbọ pe ija Joshua ati Usyk yoo ti waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹsan-an naa.
 
Usyk lo pe Joshua nija wi pe oun fẹẹ fi agbara han Joshua, ati pe oun fẹẹ gba awọn bẹliti to fi n ṣakọ sawọn alagbara bi i toun lọwọ ẹ.
 
A gbọ pe ija kan to yẹ ko waye laaarin Joshua ati Tyson Fury lakooko yii ni ko lee waye mọ, oṣu to kọja ni erongba naa dohun igbagbe.
 
Joshua sọ pe
"A ti mu ọjọ, a si ti de e."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI