Ẹ kú oríire o, ẹ kú ọdún, àṣèyí-ṣàmọ́dún - Gómìnà AbdulRazaq kí gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 20, 2021

Ẹ kú oríire o, ẹ kú ọdún, àṣèyí-ṣàmọ́dún - Gómìnà AbdulRazaq kí gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti ki gbogbo awọn ẹlẹsin musulumi jakejado orileẹ-ede yii, paapaa nipinlẹ Kwara ku oriire ti ayẹyẹ ọdun Ileya to wa nita yii. Bẹẹ lo gbadura fun wọn pe ẹmi wọn yoo ṣe pupọ rẹ laye ati laaye rere.
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita laaarọ oni, Tusidee, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo tun ti gba gbogbo eeyan lamọran wi pe ki wọn kiyesara daadaa nitori pe ajakalẹ arun korona ṣi wa nita.
 
Siwaju si i lo sọ pe ki wọn ri i daju pe wọn lo anfaani asiko yii tubọ jẹ ki ifẹ ati iṣọkan jinlẹ laaarin wọn daadaa. O ni ki wọn ri i daju pe gbogbo awọn ilana ti wọn ba mọ pe wọn le ṣe lati dẹkun ajakalẹ arun korona ni ki wọn maa ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI