Iléyá! VGN báwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí yọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ṣèlérí ààbò tó péye fáwọn aráàlú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 20, 2021

Iléyá! VGN báwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí yọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ṣèlérí ààbò tó péye fáwọn aráàlú


Ileeṣẹ eleto aabo Fijilante lorilẹ-ede yii, Vigilante Group of Nigeria, VGN ti ba gbogbo awọn ẹlẹsin musulumi kaakiri orilẹ-ede yii yọ fun ti pọpọṣinṣin ayẹyẹ ọdun Ileya to wa nita lakooko yii.
 
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ naa lapapọ, Kọmanda Nureni Ọlanrewaju Adedoyin fi sita, eyi to fi ranṣẹ si AWIKONKO lalẹ ana, Mọnde lo ti jẹ ka mọ pe gbogbo eto lo ti pari lori eto aabo to peye lasiko ayẹyẹ yii.
 
Adedoyin sọ pe, ọga awọn, Ọmọwe Usman Muhammad Jahun ti ki gbogbo awọn ẹlẹsin musulumi jakejado orilẹ-ede yii, to si gbadura fun alaafia ai iṣọkan to lọọrin laarin gbogbo eeyan patapata.

Ninu atẹjade naa lo ti sọ pe ọga awọn tun ti paṣẹ pe ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ wọn patapata fọwọsowọpọ, ki wọn si ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn eleto aabo yooku bi ọlọpaa lati le ri i daju pe ko si wahala tabi rogbodiyan lakooko ọdun Ileya naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI