Ẹ tún gbọ́ tuntun nípa bí wọ́n láwọn ọlọ́pàá Kutọnu ṣe fi Sunday Igboho sílẹ̀ wọ Germany - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 20, 2021

Ẹ tún gbọ́ tuntun nípa bí wọ́n láwọn ọlọ́pàá Kutọnu ṣe fi Sunday Igboho sílẹ̀ wọ Germany


Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe inu idunnu ati ayọ nla lawọn ololufẹ gbajugbaja ajijangbara ominira ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho yoo wa kaakiri agbaye.
 
Loootọ la gbọ pe ọwọ ọlọpaa Kutọnu, orilẹ-ede Benin tẹ Sunday Ighoho ni papakọ ofurufu, lakooko to fẹ maa lọ si Germany, nibi to tun ti niwe igbeluu miiran.
 
Koda, agbẹjọro rẹ, Pẹlumi Ọlajẹngbesi fidi iroyin ọhun mulẹ laaarọ oni, lẹyin toun naa ti ṣe iwadii.
 
Ṣugbọn sibẹ, iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii fi ye wa pe ni kutu idaji oni lawọn ọlọpaa Benin fi ọkunrin naa silẹ lati maa lọ si Germany to ti pinnu lati lọ. Ti a si gbọ pe Igboho ti fi fọto ara rẹ lakooko to wa ninu ọkọ baluu ranṣẹ si ọkan lara awọn to sunmọ ọn daadaa gẹgẹ bi aridaju wi pe oun ko si lahamọ awọn ọlọpaa kankan.
 
Awọn laaarin wakati meji si akooko yii, o ṣee ṣe ki baalu ti Igboho wọ lọ si Germany balẹ, koun funra rẹ si sọrọ jade wi pe alaafia ni oun wa.
 
A tiẹ tun gbọ pe awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa ni Germany ti tẹle iyawo rẹ lọ si papakọ ofurufu ti Sunday Igboho yoo de si lati pade rẹ, ki wọn si gbe e lọ sile rẹ to wa lọhun.



Bakan naa ninu iroyin mi in, ni ọkan lara awọn agba ilẹ Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti sọ pe o ṣee ṣe kawọn ọlọpaa Benin ba yọnda Sunday Igboho silẹ fun ijọba Naijiria, nitori ofin ilẹ wọn.
 
Akintoye sọ pe: 
"Ọkan mi daru nigba ti mọ gbọ pe wọn mu Oloye Sunday Adeyẹmọ ti wọn n pe ni Sunday Igboho ni papakọ ofurufu Kutọnu lalẹ ana (Mọnde).

"Emi ati awọn ọmọ Yoruba atata kan ta a ri ara wa pe ti bẹrẹ iṣẹ bayii lati ṣeranwọ to yẹ, ka si ri i daju pe ẹnikẹni o ṣe aburu kankan fun un tabi ṣe ohun to lodi sofin nipa ẹ, a o si ni i jẹ ki wọn dọgbọn gbe e wa si Naijiria, tori a mọ pe ohun ti wọn fẹẹ ṣe niyẹn.

"Inu wa dun pe Orileede Olominira Bẹnẹ (Benin) maa n bọwọ fun ofin, wọn si ṣee fọkan tan. A ti gba awọn lọọya to dantọ gidi, a si mọ pe wọn kaju ẹ lati boju to ọrọ yii.

"Ohun to kan bayii ni kawa ọmọ Yoruba nile ati lẹyin odi wa niṣọkan, ka dide papọ, ka figbanu kan ṣoṣo ṣ’ọja, ka fohun kan sọrọ, pe a o ni i gba ki iya kan jẹ Sunday Igboho tabi ẹnikẹni nilẹ Yoruba, a o si ni i jẹ ki wọn ṣe aidaa sọmọ Oodua eyikeyii, tabi ki wọn ṣe e yankanyankan. Lagbara Ọlọrun, orileede to lagbara lawa Yoruba, a gbọdọ gbera lati fi okun ati agbara wa han.

"Lakọọkọ, a gbọdọ ri i pe wọn fi Sunday Igboho silẹ, ko wa lominira pada, ko rin, ko yan fanda, tori a mọ pe ko dẹṣẹ kan.

"A mọ pawọn eeyan kan ni wọn fẹẹ ko o ni papamọra, wọn fẹẹ pa a danu latari bo ṣe figboya dide nitori awọn eeyan ẹ, awọn obinrin, atawọn ọmọde tawọn olubi ẹda n pa nipakupa, ti wọn n fipa ba lopọ nilẹ baba wọn, ti wọn si ba ọrọ-aje wọn jẹ. Awọn eeyan ti wọn o mọ ju ki wọn pa ẹya kan run lọ, tabi ki wọn jẹgaba le ọmọlakeji lori, bẹẹ awọn to n dari wa lo n daabo bo wọn ti wọn fi raaye nayẹ apa wọn.
 
"Bakan naa la si ti fi ọrọ akọlu ti wọn ṣe fun Sunday Igboho to ilẹ-ẹjọ agbaye to n ri si iwa ọdaran (International Criminal Court) leti, wọn ti n ṣagbeyẹwo iwe ẹsun ta a kọ."

  

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI