Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti fidi rẹ mulẹ wi pe eeyan ti ko din ni marun-un lo ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba tirela to sare wọnu ọja Bode to wa ni Mọlete, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lanaa, ọjọ Aiku, Sannde.
AWIKONKO gọ pe agbegbe Idi-Arere ni tirela naa ti n bọ ko to sọ ijanu rẹ nu lori ere asapajude, to si mu ori wọnu ọja naa, nibi to ti ṣeku pa awọn marun-un, tawọn mi in si farapa yannayanna.
Adewale Ọṣifẹsọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fidi iroyin yii mulẹ sọ pe loju ẹsẹ ni wọn ti ko awọn to farapa lọ si ọsibitu fun itọju, ti wọn si ko awọn oku lọ mọṣuari.
Ọkan lara awọn to gba ibi iṣẹlẹ naa sọda sọrun alakeji ni ọdọmọbinrin ti ẹ n wo yii, Adewumi Barakat lorukọ ẹ.
Lara awọn ọrẹ rẹ lo jẹ ko ye wa pe inu ọja Bode loun naa wa lasiko iṣẹlẹ ọhun, ati pe o wa lara awọn ti tirela naa tẹ pa.
No comments:
Post a Comment