Mo ti yọwọ patapata lọrọ oṣelu, ẹ dakun, ẹ ma ko ba mi o - Ọbasanjọ pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, July 5, 2021

Mo ti yọwọ patapata lọrọ oṣelu, ẹ dakun, ẹ ma ko ba mi o - Ọbasanjọ pariwo sita


Aarẹ tẹlẹri lorileede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe irọ nla to jinna si otitọ ni wi pe oun n gbero lati da ẹgbẹ oṣelu tuntun silẹ lori idibo ọdun 2023 to n bọ lọna.
 
Ọbasanjọ lo pariwo sita laaarọ oni, ọjọ Aje, Mọnde wi pe oun ti yọwọ oun patapata kuro lọrọ to ni i ṣe pẹlu oṣelu, nitori naa, ko si idi kan ni pato foun lati tun maa gbero lati da ẹgbẹ oṣelu miiran silẹ.
 
Baba naa to wa ni Kabul lorileede Afghanistan sọ pe oun ti ṣe odaarọ fun ọrọ ẹgbẹ oṣelu, nitori naa, oun ko tun le lọ maa sọ pe ẹkaalẹ mọ, ati pe o di aye atunwa.
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Oloye Ọbasanjọ, Ọgbẹni Kayọde Akinyẹmi gbe jade laaarọ oni lo ti sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba iroyin naa gba, ati pe awọn to n fẹ koun pada sinu oṣelu ni wọn wa nidi iroyin naa, eyi to ni ala ti ko le ṣẹ ni.
 
Laipẹ yii ni iroyin naa jade sita wi pe Ọbasanjọ ti n gbero lati da ẹgbẹ oṣelu mi in silẹ fun ti idibo to n bọ lọdun 2023, ti iroyin naa si sọ pe awọn gomina tẹlẹri mẹta lorileede yii lo fẹẹ lo lati ṣe adari ati alakooso ẹgbẹ oṣelu naa. 
 
O lawọn alagabagebe ni wọn n fẹ fi aṣọ oun yi ẹrẹ oṣelu, eyi to loun ko ni i laju silẹ lati gba fun wọn.
  
"Lọdọ temi, bi eeyan ba ti sọ pe o daarọ nibi kan, ko tun yẹ kiru ẹni bẹẹ pada lọ ṣe ẹ kaalẹ mọ. Ṣe lo yẹ ki ẹni to kọ iroyin naa lo fi ara rẹ han Yaba apa osi. Ati pe awọn to gba iroyin naa gbọ le gba wi pe ọkunrin ni mama awọn.
 
"Emi ti ṣe iwọn ti mọ le ṣe lọrọ oṣelu, ṣugbọn ipo ti mo di mu ni Naijiria, Afrika ati lagbaaye lai gberaga, mo ni lati ṣilẹkun mi silẹ fun gbogbo awọn to ba fẹẹ wa gba amọran lọwọ mi, ti maa si sọ oju abẹ nikoo fun wọn."

1 comment:

PÍN-IN KÁÀKIRI