Nítorí ayẹyẹ ọjọ́-ìbí ẹ̀: Ẹ gbọ́ bí Fáyẹmí ṣe ṣàpèjúwe Akérédolú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, July 21, 2021

Nítorí ayẹyẹ ọjọ́-ìbí ẹ̀: Ẹ gbọ́ bí Fáyẹmí ṣe ṣàpèjúwe Akérédolú


Lonii, Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu keje, ọdun 2021 ni Gimina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu pe ọdun marundinlaadọrin
(65) loke eepẹ. Pupọ awọn ololufẹ, alatilẹyin atawọn afẹnifẹre rẹ ni wọn ti n fi oriṣiriṣi ọrọ idunnu ranṣẹ si i.

Gomina Kayọde Fayẹmi tipinlẹ Ekiti naa ko gbẹyin ninu awọn to fi ọrọ ikini ati idunnu ranṣẹ si i lati ba a yọ fun anfaani to ri gba, paapaa gẹgẹ bi gomina lorilẹ-ede Naijiria.
 
Alaga igbimọ awọn ẹgbẹ awọn gomina lorilẹ-ede yii ni Arakunrin Akeredolu.
 
Ninu atẹjade ikini naa ti akọwe iroyin Gomina Fayẹmi, Ọgbẹni Yinka Oyebọde fi ranṣẹ si sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti ṣapejuwe Akeredolu gẹgẹ bi akikanju to ṣee gbẹkẹ le, to si tun ni itara lati mu idagbasoke ba agbegbe yoowu to ba ti ba ara rẹ.

O ni Akeredolu ti lo pupọ igbesi aye rẹ lati fi ja fun awọn eeyan, paapaa nigba to wa nileewe gẹgẹ bi agbẹnusọ fawọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ, to tun n pe fun ijọba rere. O ni bi ayipada rere ko ba waye, Akeredolu ko ni i panumọ, ayafi bijọba ba ṣe ohun toun pẹlu akẹgbẹ rẹ ba n fẹ.

Bẹẹ lo tun ṣapejuwe Akeredolu gẹgẹ bi jagunjagun to ni akikanju, ohun lo n ja fun ẹtọ awọn eeyan, ẹni ti ki i gboju kuro tabi ṣenupo lati sọ otitọ nita gbangba, paapaa lasiko to ba yẹ, lai wo ti ẹni to wa niṣakoso.
 
O wa a gbadura alaafia ati ẹmi gigun fun gomina Akeredolu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI