Ile ni mo wa nigba tawọn ṣọja, ọtẹlẹmuyẹ wa, ṣugbọn mo sa asala fun ẹmi mi ni - Igboho - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 1, 2021

Ile ni mo wa nigba tawọn ṣọja, ọtẹlẹmuyẹ wa, ṣugbọn mo sa asala fun ẹmi mi ni - Igboho


Oloye Sunday Igboho, olori ajijangbara ilẹ Yoruba ti sọ pe inu ile loun wa lasiko tawọn oṣiṣẹ eleto aabo ilẹ yii wa ka oun mọle laaarin oru oni.

Laipẹ yii ni Igboho sọrọ naa lasiko to n ba akọroyin BBC sọrọ nipa bi wọn ṣe pa awọn eeyan, ti wọn si tun ji iyawo rẹ gbe salọ.

O ni awọn oṣiṣẹ ologun ti wọn n pe ni ṣọja ati awọn ọtẹlẹmuyẹ ni wọn wa ka oun mọle, ti wọn n fi iku wa oun kaakiri lai mọ nnkan toun ṣe.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Lojiji ni mo kan n gbọ iro ibọn, to n dun lakọ-lakọ niwaju ile mi. Wọn n pariwo 'Igboho jade o, jade sita, awa ṣọja ati DSS ni, jade wa si wa'.

"Bi mo ṣe n gbọ ariwo naa ni mo yọju loju ferese mi, ti mo si ri wọn ninu aṣọ DSS ati ṣọja. O ya mi lẹnu gidi nitori pe mi o paayan, bẹẹ ni mi o ba eeyan kankan ja. Nnkan ti mo n ṣe ni pe mo kan n ja fawọn eeyan mi lasan ni.

"Awọn iwọde ti mo n ṣe, alaafia ni, mo n ja fun mọlẹbi ni, nitori pe awọn agbebọn ti pa awọn eeyan mi, wọn fipa ba wọn lopọ, bẹẹ ni wọn tun ji wọn gbe, ti wọn si n gba owo lọwọ wọn.

"Ijọba kọ lati ṣe nnkan to yẹ, idi ree ti mo fi jade lati ṣatilẹyin fun awọn ẹbi mi, ki n si ja fun ẹtọ wa. O ya mi lẹnu gidi.

"Bẹẹni, inu ile ni mo wa nigba ti wọn de. Wọn pa awọn eeyan meji. Ibọn ti wọn n yin naa pọ gidi. Wọn ba gbogbo dukia mi jẹ, to fi mọ awọn mọto mi. Mo sa asala fun ẹmi ara mi ni."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI