Ko sẹni to le da iwọde 'Yoruba Nation' duro l'Ekoo, Satide ni yoo waye bi a ṣe laa kalẹ - Igboho - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, July 2, 2021

Ko sẹni to le da iwọde 'Yoruba Nation' duro l'Ekoo, Satide ni yoo waye bi a ṣe laa kalẹ - Igboho


Olori ajijangbara idasilẹ orileede Oduduwa ti a  mọ si 'Yoruba Nation', Oloye Sunday Adeyẹmọ Adeniyi, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho ti sọ pe ko si iye nnkan to ṣẹlẹ, tabi oniruuru iroyin to n lọ kaakiri, eyi to le da iwọde alalaafia tawọn ti la kalẹ duro nipinlẹ Eko.

Bẹ o ba gbagbe, oru ana lawọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lọ sile Igboho, nibi ti wọn ti lọ ba ibẹ jẹ, ti wọn si pa eeyan meji, pẹlu pe wọn tun ko awọn mẹtala mi in.

Ana kan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko kkilọ fun gbogbo awọn to le maa gbero lati ṣe iwọde niluu Eko, ki wọn lọ jawọ, ati pe ẹni tọwọ ba tẹ yoo foju winna ofin.

Nigba to n sọrọ laaarọ oni, agbẹnusọ Igboho, Ọlayọmi Koiki sọ pe bawọn ṣe ti la eto iwọde naa kalẹ ni yoo ṣe lọ lai ni idaduro kankan ninu.
 
O sọ pe Ọjọta tawọn ti ṣeto rẹ silẹ naa ni yoo ti waye ni wọọrọwọ bawọn ti ṣe n ṣe e tẹlẹ kaakiri awọn ilẹ Yoruba ti wọn ti ṣe iru ẹ sẹyin.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Mo le fi da a yin loju pe iwọde ta a fẹ ṣe l'Ekoo yoo waye, eyi ti ko ni i ṣe pẹlu awọn iroyin tabi awuyewuye to ti n lọ nigboro tẹlẹ, a maa ṣe e bi a ti laa kalẹ.
 
"Gbogbo eto lo ti to patapata nipa iwọde naa. Mo ti ba awọn alabojuto eto naa sọrọ, ko si nnkan to yi pada gẹgẹ bi wọn ṣe sọ. Ọjọ kẹta, oṣu keje bẹrẹ lati deede aago mẹsan aarọ. Gbogbo eto naa lo si ti n lọ lọwọ.
 
"Mo ti ba akọwe ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, George Akinọla sọrọ, bakan naa laaarọ oni, mo ti ba Ọjọgbọn Banji Akintoye sọrọ, wọn si lawọn ti n ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe wọn tu awọn ti wọn ko lọ silẹ.
 
"Iwọde ti Eko yii yoo lọ wọọrọwọ, iwọde nla ni yoo si jẹ, ẹ ma ṣe jẹ ki nnkan to ṣẹlẹ yẹn ṣi yin lọkan. Oriṣiriṣi idagbasoke lo ti waye nile Igboho.
 
"O ṣee ṣe ka gbe fọnran jade nibi ti Igboho yoo ti sọrọ nipa iwọde naa, a maa maa gbero rẹ laaarin wakati mẹrinlelogun si igba ti a wa yii.
 
"Igboho ni ki n sọ fun gbogbo yin wi pe ki ẹ ma ṣe jẹ ki ohunkohun ba yin lọkan jẹ, oun ṣi n duro digbi lori ipinnu Yoruba Nation."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI