Ipade gbogboogbo ẹgbẹ oṣelu APC maa waye kaakiri ipinlẹ to wa laaarin gbungbun Ariwa Naijiria - Bello - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 5, 2021

Ipade gbogboogbo ẹgbẹ oṣelu APC maa waye kaakiri ipinlẹ to wa laaarin gbungbun Ariwa Naijiria - Bello


Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sani Bello ti sọ pe ko si nnkan to le da ipade gbogboogbo ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC yoo waye kaakiri gbogbo ipinlẹ to wa ni aarin gbungbun Ariwa orileede Naijiria.

Bello sọ eyi di mimọ lati tako ọrọ ti Alaaji Lai Mohammed, minisita feto iroyin, aṣa ati irin ajo afẹ lorileede yii sọ wi pe ipade gbogboogbo kankan ko ni i waye, ayafi bi wọn ba tun eto iforukọsilẹ ẹgbẹ naa ṣe.

Lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn alaga fidihẹ ẹgbẹ naa lẹkun aarin gbungbun Ariwa orileede yii, to fi mọ ilu Abuja ni Bello ti sọrọ naa naa jade.

Bello sọ pe ko si iye nnkan teeyan kankan le sọ nipa wi pe ipade gbogboogbo naa ko ni i waye, to le fẹsẹ mulẹ, bi ko ṣe pe kawọn wa ọna lati yanju awọn aawọ to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa lawọn ipinlẹ kọọkan.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ wi oe ọna tawọn yoo gba ṣe ipade naa yoo lọ nibamu pẹlu eto ijọba awaarawa lai si ẹlẹyamẹya ninu ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI