Lọ fi ara rẹ silẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ DSS ni kiakia - Olowu Kuta ṣe ikilọ nla fun Igboho - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 5, 2021

Lọ fi ara rẹ silẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ DSS ni kiakia - Olowu Kuta ṣe ikilọ nla fun Igboho


Olowu tilu Owu Kuta nipinlẹ Ọṣun, Ọba Hameed Maoama ti gba olori olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho lamọran lati fi ara rẹ silẹ fun awọn oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa, iyẹn DSS ko to pẹ ju.

Kabiyesi naa to tun jẹ olori awọn ọba Owu nipinlẹ Ọṣun lo sọrọ yii lakooko to n bawọn akọroyin sọrọ ninu aafin rẹ to wa ni Owu Kuta, ijọba ibilẹ Aiyedire, ipinlẹ naa.

O ni ki gbogbo awọn to n gbero lati da orileede Yoruba silẹ lọ ba ijọba apapọ ṣe ipade, ki wọn si tọwọ bọ iwe adehun lori nnkan ti wọn n fẹ.
 
Olowu Kuta tun sọ pe ko sẹni to ti i ṣe ipade nipa wi pe ki ipinya de ba orileede Naijiria, nitori pe gbogbo ọba patapata lo nigbagbọ ninu ifọwọsowọpọ orileede Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ko si ijọba to mọ nnkan to n ṣe, to maa fẹ ki ija tabi rogbodiyan ṣẹlẹ lorileede rẹ. Ṣe ni ọrọ awọn ti wọn n jija iyapa dabi ẹni to fẹẹ kogun ja orileede yii ni.

“Ko sẹni naa to too gbena woju agbara ijọba, to yege ri. Naijiria ko ni i jokoo lati fọwọlẹran maa woran, lẹyin ogun agbaye, ki ogun abẹle mi in tun wa a koju wọn.

“Awọn agbebọn atawọn Boko Haram ti a ni yẹ ko kọ wa lọgbọn. Fun idi eyi, maa gba gbogbo awọn ti wọn n fẹhonu han lati lọọ ba ijọba apapọ ṣe ipade.

“Ki Sunday Igboho finu-fẹdọ fi ara rẹ silẹ fun ijọba lati mu. O ṣi maa ri oju aanu gba to ba fi ara rẹ silẹ ju ki wọn lee mu lọ. Dipo ka maa pe fun ipinya, maa fọwọ si atunto, nitori pe bi a ba ṣe atunto, agbara maa de. Bi agbara ba si ti de, o di dandan ki owo pọ rẹpẹtẹ.

“Awọn ijọba ipinlẹ, paapaa lẹkun iwọ oorun wa yii ti pa awọn ijọba ibilẹ run, eyi si ni olori awọn iṣoro ti a ni. Idi ẹ ni maa ṣe fọwọ si atunto."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI