Igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC tẹlẹ ni Ariwa ipinlẹ Kwara, Suleiman Wambai ti sọ pe irọ nla to jinna si otitọ ọrọ ni alaga ana fẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Kwara, Ọnọrebu Bashir Bọlarinwa n pa kaakiri wi pe awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa lati ilu Abuja fun gomina AbdulRahman AbdulRazaq ni owo lati fi polongo idibo lọdun 2019.
Ana ti i ṣe Wẹside ni Wambai sọrọ naa jade lati le fi idi ododo mulẹ nipa awuyewuye to n jade lori eto ipolongo ibo ti Gomina AbdulRazaq tu aṣiri rẹ sita laipẹ yii.
Wambai sọ pe owo ti ẹgbẹ oṣelu APC fi ranṣẹ sawọn ẹgbẹ naa kaakiri orileede yii ni wọn fi ṣe awọn eto to ba yẹ, paapaa lati ra awọn nnkan ti wọn nilo fun idibo, eyi to pe ni sisan owo fawọn aṣoju ẹgbẹ lawọn agbegbe idibo, awọn alakoso eto ibo, atawọn ti yoo bawọn eeyan sọrọ lori bi wọn yoo ṣe dibo wọn.
O ni bi owo naa ṣe wọle ni wọn ti fi ilana bi wọn yoo ṣe naa tẹle e, ati pe awọn agbaagba ẹgbẹ to fi mọ awọn alẹnulọrọ lo ṣakoso bawọn owo naa ṣe di lilo fawọn nnkan to wa fun.
O wa sọ siwaju pe irọ nla to jinna si otitọ ọrọ ni alaga ana fẹgbẹ naa nipinlẹ Kwara, Ọnọrebu Bashir Ọmọlaja Bọlarinwa n pa kaakiri wi pe Gomina AbdulRazaq ko sọ bo ṣe na owo to gba lati ọdọ apapọ ẹgbẹ naa lati ilu Abuja.
Siwaju si i lo sọ pe bi owo naa ṣe wọle, ati bi wọn ṣe na awọn owo naa ko ṣẹyin gbogbo ọmọ ẹgbẹ patapata, nitori pe ko si nnkan ti wọn fi pamọ nibẹ rara fẹkinkẹni, ati pe akọsilẹ ṣi wa.
Wambai sọ pe ipinlẹ Kwara ko gba biliọnu kan naira bi awọn kan ṣe n sọ kaakiri, ati pe akọsilẹ bi owo naa ṣe wọle ṣi wa nile ẹgbẹ fẹnikẹni lati ri i.
No comments:
Post a Comment