Oludije sipo gomina ipinlẹ Kwara lọdun 2019, Ambasidọ Mohammed Abubakar Mohammed ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara, ti gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq si ti tẹwọ gba a wọle.
Ana ti i ṣe Satide, Abamẹta ni iroyin naa tẹ AWIKONKO lọwọ, ti inu gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa si dun, koda ti ẹsẹ ko gbero nibi ayẹyẹ eto igbaniwọle ti wọn ṣe fun un.
Níbẹ ni Mohammed ti ṣalaye idi pataki to fi darapọ mọ ẹgbẹ naa, wi pe awọn idagbasoke toun n ri lo fi ọkan oun balẹ lati wọnu ẹgbẹ APC.
O ni aṣeyọri ti ijọba APC ti ṣe laaarin ọdun meji ti wọn bẹrẹ iṣejọba wu oun lori pupọ, to si ti la oju awọn araalu si idagbasoke to peye.
Siwaju si i lo sọ pe oju awọn eeyan ilu naa di tẹlẹ lasiko awọn iṣakoso to ti kọja lọ, ṣugbọn ti ijọba APC ti la gbogbo wọn loju pe inu igbekun lawọn wa lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin, eyi loo jẹ iwuri foun naa lati darapọ mọ ẹgbẹ onidagbasoke naa.
Nigba toun naa n sọrọ, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe idunnu nla lo jẹ fawọn lati gba iru oludije tawọn jọọ figagbaga ninu idibo to kọja wọle sinu ẹgbẹ, to si lawọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ papọ fun idagbasoke.
No comments:
Post a Comment