Awọn ọdọ ẹgbẹ oṣelu APC bẹrẹ ipolongo idibo ẹlẹẹkeji fun AbdulRazaq ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 4, 2021

Awọn ọdọ ẹgbẹ oṣelu APC bẹrẹ ipolongo idibo ẹlẹẹkeji fun AbdulRazaq ni Kwara


Apapọ ẹgbẹ awọn ọdọ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ṣetan lati ṣagbatẹru Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ naa lẹẹkeji.

Wọn ni gbogbo awọn akanṣe iṣẹ ti Gomina AbdulRazaq n ṣe kaakiri ipinlẹ naa lo n mu ori awọn wu, nitori pe ki i ṣe ojuṣaaju lawọn iṣẹ naa jẹ.

Nibi akanṣe eto kan to waye nilu Osi, ijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ naa, eyi ti wọn pe ni Ekiti Kwara Colloquium laipẹ yii lawọn ọdọ naa ti sọ pe gbogbo nnkan ti yoo ba gba lawọn yoo fi ṣatilẹyin fun AbdulRazaq.

Eto naa ti wọn pe akọle rẹ ni "REDEFINING EKITI FOR SOCIO-POLITICAL AND ECONOMIC EMPOWERMENT" lawọn ọdọ naa ti olori wọn, Adetunji Ogundeji ati Busayo David toun jẹ akọwe ti sọrọ.

Wọn ni ijọba ibilẹ naa ko ti i ni iru idagbasoke ti gomina ṣe fawọn yii ri latigba ti wọn ti bẹrẹ eto oṣelu alagbada.

Siwaju si i ni wọn sọ pe gbogbo igba tawọn ba ti n ri awọn iṣẹ meremere ti Gomina AbdulRazaq n ṣe kaakiri, lawọn maa n bu sẹkun, nitori pe ṣe ni yoo tun jẹ kawọn ranti awọn iya ti wọn ti n jẹ bọ sẹyin labẹ akoso awọn ijọba to ti kọja lọ.

Wọn wa sọ pe awọn bẹrẹ imurasilẹ silẹ lati le jẹ ki AbdulRazaq maa teṣiwaju ijọba rẹ kọja ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI