Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ki gbogbo awọn alaṣẹ tuntun fun ti igbimọ iṣakoso Kwara State Chamber of Commerce, Industry, Mines and Agriculture (KWACCIMA) ti wọn ṣẹṣẹ yan laipẹ yii.
O ṣapejuwe ileeṣẹ naa gẹgẹ bi ọkan lara awọn igilẹyin ọgba ileeṣẹ to n ṣagbatẹru ijọba.
Laipẹ yii lawọn ọmọ ẹgbẹ naa yan igbimọ tuntun, eyi ti Alaaji Ọlalekan Fatai Ayọdimeji jẹ Aarẹ tuntun.
"A ki igbimọ tuntun KWACCIMA yii kaabọ labẹ alakoso, Aarẹ wọn, Alaaji Ọlalekan Fatai Ayọdimeji. Mo si n gba yin lamọran wi pe ki ẹ tubọ maa di ara yin mu ṣinṣin, bẹẹ ni ki ẹ si maa wa ni irẹpọ lati ri i pe idagbasoke n deba awọn ileeṣẹ kereje ati nla-nla.
"Gẹgẹ bi ẹ ti mọ pe ijọba yii bikita pupọ lori idasilẹ awọn ileeṣẹ aladani kereje-kereje, ati idagbasoke wọn. Eyi la fi n gbagbọ pe pẹlu igbimọ tuntun yii, ileeṣẹ yoo tun pọ si."
No comments:
Post a Comment