Bi idibo gomina nipinle Anambra ṣe n sunmọ etile, Gomina ipinle Yobe, Mai Mala Buni ti kede awọn gomina meji ọtọọtọ, Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ati AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara lati dari bi wọn yoo ṣe yanju aawọ to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.
Mai Mala Buni ni alaga igbimọ ti yoo ṣakoso eto ipade gbogboogbo ẹgbẹ naa kaakiri orileede yii.
Bi idibo abẹle ẹgbẹ APC to fẹẹ waye nipinlẹ Anambra lọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun yii ṣe n sunmọ etile, ati lati le tete yanju awọn aawọ to ti n dide ninu ẹgbẹ naa lo jẹ ki Gomina Mai Mala Buni yan Gomina Sanwo-Olu ati Gomina AbdulRazaq lati wa iyanju si i, ki gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa si le wa ni iṣọkan.
Buni sọ pe awọn gomina mejeeji gbọdọ ri i daju pe wọn mu iṣọkan, alaafia ati irẹpọ ba gbogbo ọmọ ẹgbẹ, to fi mọ awọn oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ ọhun.
No comments:
Post a Comment