Laaarin emi ati AbduRazaq, ija ṣẹṣẹ bẹrẹ ni - Lai Mohammed pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ




Sunday, July 4, 2021

Laaarin emi ati AbduRazaq, ija ṣẹṣẹ bẹrẹ ni - Lai Mohammed pariwo sita


Minisita fọrọ eto iroyin, aṣa ati irin ajo afẹ lorileede yii, Alaaji Lai Mohammed ti sọ pe ija to wa laaarin oun ati gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.
 
Mohammed lawọn yoo ṣe eto iforukọsilẹ miiran fawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC atawọn ọmọ ẹgbẹ tuntun to ba fẹẹ wọle.
 
Nibi ti Mohammed ti lọ ṣi ile ẹgbẹ tuntun lanaa ti i ṣe Satide niluu Ilọrin lo ti sọrọ naa jade, to si loun ko le maa wo ọkunrin naa, iyẹn AbdulRazaq niran.
 
O ni eto iforukọsilẹ ti wọn ṣe nipinlẹ naa laipẹ yii ko lọ bo ṣe yẹ ko lọ, ati pe wọn fi ẹtọ awọn eeyan, paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ naa dun wọn, leyi to sọ pe ko bojumu to.

Bẹ o ba gbagbe, ẹgbẹ oṣelu APC ti igun Lai Mohammed ṣe ayẹyẹ ọdun keji ti wọn ti gba ijọba nipinlẹ naa, eyi ti wọn ko pe awọn ti Gomina AbdulRazaq sibẹ.
 
Ayẹyẹ ti wọn ni ile ẹgbẹ to wa ni Tanke lawọn igun Gomina AbdulRazaq ṣagbatẹru ẹ, nigba ti Lai Mohammed lọọ ṣi ile ẹgbẹ tuntun tiẹ sinu GRA to wa nilu Ilọrin.
 
Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe "Eto iforukọsilẹ ti a ṣe kọja yii ko lọ bo ṣe yẹ ko lọ, nitori pe ṣe ni wọn ko fun awọn ọmọ ẹgbẹ lanfaani lati forukọsilẹ, nitori pe wọn ko fun wọn lawọn irinṣẹ eto iforukọ silẹ.

"Nigba ti mo ri nnkan to ṣẹlẹ yii, emi ati awọn oludije sipo gomina meji kan Ọjọgbọn Ọba AbdulRaheem ati Alaaji Tajudeen Audu la jọ lọ ba alaga ẹgbẹ naa, Alaaji Mai Mala Buni, to si fidi ẹ mulẹ wi pe awọn yoo ṣe eto iforukọsilẹ miiran fawọn Kwara.
 
"Awa ko mọ ọn ri tẹlẹ, ko ni ọfiisi ipolongo idibo. A ti jọ kẹsẹ bọ ṣokoto kan naa; lai si ẹyin, ọmọ ẹgbẹ, ko le si nnkan to n jẹ APC nipinlẹ Kwara. Mo fẹẹ fi da a yin loju pe ko si ipade gbogboogbo kan ti yoo waye fawọn ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara, ayafi bi eto ifọrukọsilẹ miiran ba waye."

Bẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja lọ ni Gomina AbdulRazaq tu aṣiri bawọn agbaagba ẹgbẹ naa ṣe owo ipolongo idibo, ti wọn ko si fun oun ninu ẹ, eyi to lo jẹ koun da ipolongo naa ṣe funra oun.

Nigba to n tako ọrọ naa, Mohammed sọ pe oun ko gba owo lọwọ ẹnikẹni fun ipolongo idibo ọdun 2019, ati pe oun ko gba owo kankan sapo ara oun, gẹgẹ Gomina  AbdulRahman AbdulRazaq ṣe fẹsun kan oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI