Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni, ẹni to tun jẹ alaga fidihẹ fun ipade gbogboogbo to fẹẹ waye fẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, iyẹn Caretaker and Extra-Ordinary Convention Planning Committee, CECPC kaakiri orileede yii ti sọ pe ko ni i ṣe pẹlu awọn awuyewuye to n lọ ninu ẹgbẹ oṣelu naa, awọn yoo ṣe ipade gbogboogbo wọn.
Lonii ti i ṣe Sande ni Buni sọrọ naa jade nilu Abuja, to si lawọn ti ṣi awọn ileeṣẹ ẹgbẹ kaakiri ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria, to fi mọ ilu Abuja ti olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa wa.
O ni gbogbo awọn awuyewuye to n lọ kaakii eto iforukọsilẹ ti wọn ṣe kọja fawọn ọmọ ẹgbẹ naa ko ni i da ipade gbogboogbo naa duro, ṣugbọn to sọ pe igbesẹ ti n lọ lori ẹ lati pana awuyewuye naa.
Bakan naa lo tẹsiwaju pe ki gbogbo ẹni to ba fẹẹ mọ awọn alaga ẹgbẹ naa ati awọn ibi tawọn ileeṣẹ ẹgbẹ naa wa kaakiri Naijiria lọ si ori ikanni ayelujara ti https://officialapc.ng/find-your-state-secretariat lati mọ.
No comments:
Post a Comment