Maluu irinwo ha sọwọ Amọtẹkun l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 4, 2021

Maluu irinwo ha sọwọ Amọtẹkun l'Ondo


Ko din ni irinwo maluu to ti ha sọwọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti wọn pe ni Amọtẹkun, ẹka tipinlẹ Ondo.
 
Oloye Adetunji Adelẹye, to jẹ adari ẹgbẹ Amọtẹkun nipinlẹ naa lo fidi iroyin yii mulẹ nilu Akurẹ, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ, to si lawọn ti bẹrẹ iwadii lori wọn.

O ni aṣẹ ijọba wi pe ki gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ bẹrẹ eto aabo ojulalakanfinṣọri ti so eso rere pẹlu iṣẹ tawọn n ṣe.

Adelẹyẹ sọ pe ojoojumọ lawọn n ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe iwa ọdaran laaarin awọn Fulani darandaran si awọn agbẹ atawọn ọmọ Yoruba dopin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI