O ma ṣe o: Tanka gaasi tẹ eeyan mẹwaa pa laaarin ọja n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 4, 2021

O ma ṣe o: Tanka gaasi tẹ eeyan mẹwaa pa laaarin ọja n'Ibadan


Tanka epo gaasi kan la gbọ o ti tẹ eeyan ti ko din ni mẹwaa pa laaarin ọja Bode to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lonii, ọjọ Aiku, Sannde.
 
A gbọ pe ṣe ni ijanu tanka epo gaasi naa ja lori ere, lagbegbe Idi Arere, to si ṣe bẹẹ mori wọnu ọja Bode to wa nitosi, nibi to ti tẹ awọn eeyan naa pa.
 
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye la gbọ pe awọn ẹlẹyinju aanu ti ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ panapana lati wa a doola ẹmi ati dukia awọn eeyan, ti wọn si lawọn eeyan naa ko fọrọ ọhun falẹ rara.
 
Awọn oṣiṣẹ eleto aabo la gbọ pe wọn gbe awọn oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu to wa nitosi, bẹẹ ni wọn ko awọn to farapa lọ si ọsibitu fun itọju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI