Wọ́n ju Noah àti Destiny sẹ́wọ̀n l'Ẹdo, ẹ̀sun 'Yahoo-Yahoo' ni wọ́n fi kàn wọ́n - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 21, 2021

Wọ́n ju Noah àti Destiny sẹ́wọ̀n l'Ẹdo, ẹ̀sun 'Yahoo-Yahoo' ni wọ́n fi kàn wọ́n


Awọn meji ti ẹ n wo yii nile-ẹjọ giga tipinlẹ Ẹdo to wa niluu Benin ju sẹwọn lori ẹsun jibiti ori ayelujara, iyẹn 'Yahoo-Yahoo', ti wọn fi kan wọn.
 
Ileṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo kumọkumọ lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC lo foju awọn mejeeji, Noah Omoregbe ati Destiny Efewengbe ba ile-ẹjọ naa lonii, niwaju Onidajọ Efe Ikponmuwonba.
  
Orukọ ẹnikan ti wọn pe ni Frank Mark, oṣiṣẹ ologun ilẹ Amẹrika la gbọ pe Noah fi n lu jibiti, to si fi gba obitibiti owo lọwọ Luid Mila lọjọ kọkanlelogun, oṣu to kọja. Foonu iPhone X ti nọmba idanimọ rẹ jẹ 354862090120911 ni wọn sọ pe o fi tẹ atẹjiṣẹ ranṣẹ si mila, eyi ti wọn loo tako ofin ọdaran, to si ni ijiya ninu.
 
Ni ti Destiny, wọn ni orukọ William Scot loun fi lu jibiti lọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun yii lagbegbe Ugbor, ilu Benin. Yaun Tested la gbọ pe oun fi ayederu atẹjiṣẹ ranṣẹ si lori foonu iPhone 11 Pro Max pẹlu nọmba idanimọ 353926104836894.
 
Awọn mejeeji la gbọ pe o bẹbẹ fun idariji ẹṣẹ, lẹyin ti wọn gba pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
 
Lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ si ile-ẹjọ, Onidajọ Ikponmwonba ju Noah sẹwọn ọdun meji gbako pẹlu iṣẹ aṣekara, bẹẹ lo si fi anfaani silẹ fun un lati san owo itanran ẹgbẹrun lọna igba, bi ko ba fẹẹ lọ ṣe ẹwọn naa.
 
O sọ Destiny sẹwọn oṣu mẹfa gbako, to si loun naa ni anfaani lati san owo itanran ẹgbẹrun lọna igba naira gẹgẹ bi owo itanran, boun naa ko ba fẹẹ lọ sẹwọn.
 
Gbogbo awọn ẹru ati dukia ti wọn gba lọwọ wọn patapata ni ile-ẹjọ paṣẹ wi pe ki wọn ko sapo ijọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI