Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba kare fun Aarẹ ilẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu lori bi awọn ologun ṣe gba awọn ajọsin ijọ Christ Apostolic Church (CAC) ti wọn jigbe niluu Eruku, ijọba ibilẹ Ekiti laipẹ yii silẹ.
Olujọsin mejidinlogoji la gbọ pe wọn ti gba itusilẹ bayii, ninu iṣẹ eto aabo tawọn ileeṣẹ eleto aabo kaakiri ilẹ Naijiria ṣe loni, ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025.
Gomina AbdulRazaq sọ pe iṣẹ akanṣe, ati ọwọ ti Aarẹ Bọla Tinubu fi mu iṣẹlẹ naa, lo jẹ ki awọn eeyan naa gba itusilẹ kuro lọwọ awọn agbebọn aṣekupani.
Aarẹ Bọla Tinubu la gbọ pe o ti wọgile ipa G20 to fẹẹ lọ fun lorileede South Africa lati gbajumọ ọrọ eto aabo to mẹhẹ nipinlẹ Kwara ati Kebbi.
Bakan naa ni aarẹ tun ti paṣẹ pe ki awọn ileeṣẹ aabo fara si iṣẹ eto aabo nipinlẹ Kwara, lati rii pe aabo to pe ye wa fun ẹmi ati dukia araalu.
Siwaju sii ni gomina tun dupẹ lọwọ awọn bii oludamọran pataki lori eto aabo nilẹ Naijiria; ileeṣẹ ologun, ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ; ati awọn ọlọpaa lori iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe.

No comments:
Post a Comment