Abubakar tó fẹ́ràn láti máa já mọ́tò gbà ní Kwara há, ló bá bú sẹ́kún - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 24, 2021

Abubakar tó fẹ́ràn láti máa já mọ́tò gbà ní Kwara há, ló bá bú sẹ́kún


Ọrọ buruku toun tẹrin nigba tọwọ awọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi nipinlẹ Kwara tẹ gendekunrin ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Abubakar Aliyu, ẹni ti wọn lo fẹran lati maa digun ja mọto gba lọwọ awọn eeyan, to si bu sẹkun.
 
Mọto ayọkẹlẹ Toyota Camry kan la gbọ pe Abubakar ja gba lagbegbe Malete, ipinlẹ naa, eyi lo si tu aṣiri rẹ tọwọ fi tẹ ẹ.
 
Nigba to n firoyin naa to awọn akọroyin leti, alukoro ileeṣẹ Sifu Difẹnsi nipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi sọ pe Ọjọru, Wẹside, ọjọ kọkanla, oṣu yii ni Abubakar ji mọto alawọ pupa naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ EPE 294 GT naa gbe.
 
O ni baale ile ni Abubakar, ati pe ọmọ meji lo ti bi. O ninu ọgba ilegbe awọn akẹkọọ KWASU, iyẹn hostel lo ti ji mọto ọhun gbe laaarin oru ọjọ naa.
 
Afọlabi tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe ọjọ keji ti iroyin naa ti tẹ wọn lọwọ lawọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, lọwọ ti pada tẹ Abubakar ninu mọto naa.

O tiẹ jẹ ko ye wa pe ṣe ni Abubakar ba ferese wọle sinu yara ẹni to ni mọto ọhun, to si ji kọkọrọ rẹ to fi gbe mọto naa salọ.
 
Bẹẹ lo tun jẹ ko di mimọ pe aarin wakati mẹjọ ti Abubakar ji mọto naa gbe lo fi yi ọda awọ pupa ara rẹ pada si awọ dudu, ati pe ọdọ ẹni to n kun mọto, ẹni ti wọn pe orukọ rẹ ni Adewunmi Taiwo Gabriel to wa ni Oko Erin nilu Ilọrin lo gbe e lọ lati yi ọda naa pada, ki aṣiri ma ba a tu.
 
Awọn mejeeji la gbọ pe wọn ti wa lahamọ awọn Sifu Difẹnsi, nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo, ko to di pe wọn foju ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI