PDP ṣetán láti gbàjọba kúrò lọwọ Buhari àti APC lọ́dún 2023 - Atiku sọ̀rọ̀ ìdánilójú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, August 24, 2021

PDP ṣetán láti gbàjọba kúrò lọwọ Buhari àti APC lọ́dún 2023 - Atiku sọ̀rọ̀ ìdánilójú


Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar ti sọ pe ẹgbẹ naa ti ṣetan lati gba ijọba kuro lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, lọdun 2023.


Atiku sọ pe PDP maa pada sipo oijọba, bẹrẹ lati ọdun 2023 lọ.
 
Nibi abẹwo to ṣe lọ sọdọ gomina ipinlẹ Edo, Godwin Ọbasẹki lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee nilu Benin lo ti sọrọ naa jade wi pe igbesẹ lati gbajọba mọ ẹgbẹ oṣelu APC lọwọ ti n lọ.

Nibẹ ni Obasẹki ti gbe oriyin fun Atiku lori awọn ipa to ko lasiko idibo to gbe e wọle lẹẹkeji, to si lawọn yoo sa gbogbo ipa wọn lati ri i pe PDP gbajọba orilẹ-ede yii pada.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI