APC: Igbimọ kotẹmilọrun yoo jokoo ipade lonii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 16, 2021

APC: Igbimọ kotẹmilọrun yoo jokoo ipade lonii


Igbimọ kotẹmilọrun ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC gbe kalẹ lati yanju awọn aawọ to waye nibi eto ipade gbogboogbo abẹle ẹgbẹ naa ti ṣetan lati jokoo lonii, ọjọ Aje, Mọnde.

Alaga igbimọ iṣakoso eto ipade gbogboogbo, Caretaker/Extraordinary Convention Planning Committee (CECPC), ẹgbẹ naa, Gomina Mai Mala Bunni tipinlẹ Yobe lo gbe igbimọ yii dide lati ri si awọn kudiẹkudiẹ to waye nibi ipade gbogboogbo abẹle kaakiri Naijiria.
 
Ilu Ilọrin nipinlẹ Kwara la gbọ pe awọn igbimọ yii yoo ti jokoo iapde naa, lati mọ ibi ti eto naa ku si, ki wọn si bawọn to n binu sọrọ asọyepọ.

Ninu atẹjade ti aalaga fidihẹ ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Kwara, Alaaji Abdullahi Samari Abubakar fi sita lo ti sọ pe awọn ọmọ igbimọ naa ti de siluu Ilọrin, ti wọn yoo si jokoo ipade ni gbọngan Banquet, bẹrẹ lati aago mẹwaa aarọ oni.
 
Bẹẹ lo sọ pe kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ Kwara ni wọn ti n reti awọn akopa. 
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI