APC pàṣẹ fáwọn olùdíje sípò ìjọba ìbílẹ̀ ní Kwara lati yọjú fún àyẹ̀wò - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 31, 2021

APC pàṣẹ fáwọn olùdíje sípò ìjọba ìbílẹ̀ ní Kwara lati yọjú fún àyẹ̀wò


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nipinlẹ Kwara ti sọ fun gbogbo awọn oludije kaakiri ipo to wa nijọba ibilẹ lati yọju fun ayẹwo finnifinni.
 
Ọjọ Aje, Mọnde, ana ni ẹgbẹ oṣelu APC paṣẹ fun gbogbo awọn oludije naa lati farahan niwaju igbimọ ti yoo ṣe ayẹwo fun wọn ko to di pe wọn bọ sori papa idibo.
 
Gẹgẹ bi Alaaji Tajudeen Aro Afọlabi to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ naa ṣe sọ, o ni laaaarin oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, si ọla, Ọjọru, Wẹside, iyẹn ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹsan-an ni anfaaani wa fun gbogbo awọn to ba fẹ jade dije du ipo lati yọju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI