Ó mà ṣe o! Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tó kẹ́kọ̀ọ́-jáde Poli, Faith dágbére fáyé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 31, 2021

Ó mà ṣe o! Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tó kẹ́kọ̀ọ́-jáde Poli, Faith dágbére fáyé


Titi dasiko taa ṣakojọpọ iroyin yii tan, inu ẹkun ati ironu nla lawọn obi ati ọrẹ ọdọmọbinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Faith Favour, ẹni ti wọn loo kẹkọ jade ni ile-ẹkọ gbogboniṣe tipinlẹ Kanduna lọsẹ meji sẹyin, to si ku lojiji.
 
Bo tilẹ jẹ pe AWIKONKO ko tii gbọ nipa aṣiri iku to pa Faith, ṣugbọn ti a gbọ pe asiko to yẹ kawọn obi rẹ fẹyinti lati maa jẹun ọmọ ni Faith dagbere faye.
 
Final year Kaduna Polytechnic student dies after signing out celebration  
Ẹka ikẹkọọ Hospitality Management la gbọ pe Faith ti ṣetan ni ile-ẹkọ gbogboniṣe naa. Ọsẹ meji ṣeyin si la gbọ pe o pari idanwo aṣekagba rẹ, nibi to ti ṣe ajọyọ pẹlu awọn ẹlẹgbẹ ẹ.
 
Ọkan lara awọn ọrẹ faith, ẹni to pe orukọ ara rẹ ni Mhister Isaac lo gbe iroyin naa sita lana, ọjọ Aje, Mọnde, nibi to ti n banujẹ lori iku Faith.


Final year Kaduna Polytechnic student dies after signing out celebration

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI