Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn fẹ̀mí èèyàn méjì ṣòfò danù n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 27, 2021

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn fẹ̀mí èèyàn méjì ṣòfò danù n'Ilọrin


Ko din ni eeyan meji ọtọọtọ taa gbọ pe wọn ti dero ọrun alakeji lojiji nibi ikọlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to kọju ija sira wọn niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.
 
Ni nnkan bi aago mẹfa irọlẹ ana, Ọjọbọ, Tọside la gbọ pe wọn pa awọn meji naa ti wọn pe orukọ ọkan lara wọn ni Abdulazeez, ṣugbọn ti a ko mọ orukọ ẹnikeji titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yii tan.
 
AWIKONKO gbọ pe iṣẹ telọ, iyẹn awọn to n ran aṣọ ta ni Abdulazeez n ṣe lagbegbe Alagbado.
 
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye ati Ẹyẹ ti fagba han ara wọn lọsan ana, Tọside ninu ọgba ile-ẹkọ kereje ti Kwara State Polytechnic's Institute of Technology.

Awọn ọlọpaa ẹkun 'C' to wa ni Ọja-Ọba la gbọ pe wọn pada wa gbe oku awọn meji naa kuro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI