Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara tẹ́lẹ̀ náà kú lójijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 27, 2021

Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara tẹ́lẹ̀ náà kú lójijì


Igbakeji gomina ipinlẹ Kwara, Oloye Joel Afọlabi Ogundeji ti jade laye.
 
Gẹgẹ baa ṣe gbọ, ilu Ilọrin, ipinlẹ naa ni Oloye Ogundeji ku si l'Ọjọbọ, Tọside ana, lẹyin aisan ranpẹ ti wọn lo daa dubulẹ lati bi ọjọ meloo kan sẹyin.
 
Oloye Ogundeji ni igbakeji gomina Bukọla Saraki laaarin ọdun 2003 si 2011.
 
Ko to gba ipo igbakeji alaga, Ogundeji ti ṣiṣẹ kaakiri oriṣiriṣi ẹka iṣẹ ijọba nipinlẹ Kwara, to si jẹ ọga agba laaarin awọn oṣiṣẹ ijọba.
 
Nigba to n kẹdun iku ẹ, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe adanu nla niku Joel Afọlabi Ogundeji jẹ nipinlẹ naa, to si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI