Ẹgbẹ awọn oniṣẹ ọwọ kaakiri ipinlẹ Kwara, Kwara State Artisan Congress ti gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori awọn akanṣẹ iṣẹ idagbasoke manigbagbe to n ṣe latigba to ti de ori ipo.
Wọn tun lu gomina naa lọgọ ẹnu pẹlu bo ṣe yi oju iṣakoso pada si ti araalu, t wọn si lawọn ṣetan lati gbaruku ti i lati tẹsiwaju lọdun 2023.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Alaaji Jimọh Adeṣina nigba to n sọrọ sọ pe awọn ko le ṣai panumọ lati sọ ododo wi pe gomina n ṣe kọja ohun tawọn eeyan lero wi pe o le ṣe, ṣugbọn to ya awọn eeyan lẹnu, pẹlu bo ṣe sọ ijọba rẹ di ijọba mẹkunnu.
Lakooko ti wọn n ba oludamọran pataki fun Gomina AbdulRazaq lori ọrọ eto oṣelu, AbdulLateef Alakawa sọrọ ni wọn ti sọrọ yoo, ti wọn si lawọn ti n gbaradi fun idibo ọdun 2023 lati le gbaruku ti i.
No comments:
Post a Comment